Adajọ ran olukọ ileewe giga Kwara to n ṣe jibiti ori ẹrọ ayelujara lẹwọn n’Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

Adajọ Sikiru Oyinloye, tile-ẹjọ giga kan to wa niluu Ilọrin, ju olukọ ileewe giga ti wọn ti n kọ nipa eto ilera, Kwara State College of Health Technology (Health Tech), to wa niluu Ọffa, Adebisi Ademọla, sẹwọn oṣu mẹfa fẹsun jibiti ori ẹrọ ayelujara.

Ademọla, ẹni ọdun mejidinlogoji, wa laarin awọn afurasi mẹtalelọgbọn tọwọ ajọ EFCC tẹ niluu Ọffa, lọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan-an, ọdun 2020.

Ọkunrin to n pe ara rẹ ni Dawn Ayero, to si n lo aworan arẹwa obinrin oyinbo kan lori intanẹẹti lati fi tan ẹnikan torukọ rẹ n jẹ Donald Oakes, pe oun nifẹẹ rẹ, to si fi n gba owo lọwọ iyẹn.

Olujẹjọ naa ti ṣaaju sọ pe loootọ loun jẹbi ẹsun naa.

Ọkan lara awọn oṣiṣe EFCC, Olumide Ọlasode, ṣalaye bawọn eeyan ṣe ta ileeṣẹ naa lolobo nipa itu tawọn ọmọ ‘yahoo’ n pa niluu Ọffa, lo mu ki ọwọ tẹ olujẹjọ naa.

Agbẹjọro ijọba, Andrew Akoja, rọ ile-ẹjọ lati dajọ rẹ pẹlu gbogbo ẹri to wa nilẹ ati ijẹwọ olujẹjọ naa.

Adajọ Oyinloye fun olujẹjọ lanfaani lati sanwo itanran ẹgbẹrun lọna aadọta naira, bakan naa ladajọ ni ijọba ti gbẹsẹ le foonu to fi n ṣiṣẹ jibiti rẹ naa.

Leave a Reply