Adajọ ran Peter lẹwọn oṣu mẹrin, kula ounjẹ lo ji gbe

Monisọla Saka

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni adajọ kootu Majisireeti kan to fikalẹ siluu Ọta, nipinlẹ Ogun, sọ ọdọmọkunrin ẹni ọdun mejidinlogun kan, Peter Ogunbiyi, sẹwọn oṣu mẹrin fun ẹsun ole jija. Lara awọn nnkan ti wọn ka mọ Peter lọwọ ni kula, irin oju windo, gilaasi aluminiọmu ti apapọ iye owo gbogbo ẹ to ẹgbẹrun lọna igba Naira (200,000). Gbogbo awọn nnkan wọnyi lo ji ko lasiko to lọọ fọle arabinrin kan to n jẹ Sarah Ọlayẹmi. 

Ọkunrin ọdaran ti wọn o sọ ibi to n gbe yii rawọ ẹbẹ sile-ẹjọ pe oun ko jẹbi ẹsun ole jija ti wọn fi kan oun yii, ki adajọ jọwọ, ṣiju aanu wo oun. Agbefọba nile-ẹjọ naa, Insipẹkitọ Ẹ. O. Adaraloye, ṣalaye pe   ni nnkan bii aago mẹrin idaji ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni Peter Ogunbiyi lọọ fọle Arabinrin Sarah Ọlayẹmi, to wa laduugbo Oloko, agbegbe Ọbasanjọ,  Ọta, nipinlẹ Ogun, to si palẹ gbogbo awọn nnkan ti wọn ka mọ ọn lọwọ yẹn mọ fefe. 

Nigba to n dajọ ọdaran ọhun, Adajọ A.O Adeyemi ni ile-ẹjọ naa ran Peter lẹwọn oṣu mẹrin lai faaye beeli silẹ fun un. O fi kun un pe iwa to hu lodi si iwe ofin ipinlẹ Ogun ọdun 2006. 

Leave a Reply