Adajọ sọ awọn baba agbalagba meji satimọle, awọn ọmọde ni wọn fipa ba laṣepọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori ti wọn fipa ba ọmọdebinrin kan sun ni tipatipa, kootu to n gbọ ẹjọ to ni i ṣe pẹlu ọrọ mọlẹbi nipinlẹ Ọyọ, ti binu sọ awọn baba agbalagba meji kan sinu ahamọ.

Alukoro ajọ sifu difẹnsi nipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Oluwọle Oluṣẹgun, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan l’Ọjọruu, Wẹsidee.

O ni awọn afurasi mejeeji yii ni wọn ti gbe lọ sile-ẹjọ, ti ile-ẹjọ si ti fi wọn pamọ sahaamọ to wa ni Abolongo, niluu Ọyọ.

Gẹgẹ bii alaye to ṣe, afurasi akọkọ, Kayọde Akinṣile, ẹni ọgọta (60) ọdun, ni wọn kọkọ mu lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹfa, ọdun yii, ti wọn si gba beeli ẹ, ṣugbọn lẹyin ti wọn tu u silẹ tan lo tun lọọ fipa ba ọmọdebinrin mi-in laṣepọ.

Ọjọ keje, oṣu yii, ni wọn tun un mu fẹsun ifipabanilopọ keji yii.

Ni ti afurasi keji, Dokita Ajelere Ajewumi, ẹni ọdun mejidinlaadọrin (68), wọn ni nṣe lo fipa ji ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹrinla kan gbe, to si fipa ba a lo pọ.

Lẹyin ti wọn ka awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn olujẹjọ mejeeji yii si wọn leti tan, adajọ kootu Majisreeti ọhun to wa laduugbo Iyaganku, n’Ibadan, Onidaajọ P.O Adetoyinbo, paṣẹ pe ki awọn agbofinro ko awọn afurasi ọdaran naa si ahamọ titi dọjọ kan ninu oṣu kẹsan-an, ọdun yii.

Leave a Reply