Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori ti wọn lu awọn eeyan ni Jibiti owo dọla lori ẹrọ ayelujara, ile-ẹjọ giga ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan, ti sọ awọn ọmọ ‘Yahoo’ mẹrin kan sẹwọn oṣu mẹfa gbako.
Lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja l’Onidaajọ Sherifat Adeyẹmi ti i ṣe adajọ ile-ẹjọ naa da sẹria ọhun fun wọn lẹyin ti ajọ to n gbogun ti magomago owo ati iwa jibiti nilẹ yii, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, fi panpẹ ọba gbe wọn, to si gbe wọn lọ sile-ẹjọ.
Orukọ awọn onijibiti mẹrẹẹrin ọhun ni Adekanbi Babatunde Aliu, Agoba Monday Fred, Oyetunji Salam Korede ati Ogbonna Friday.
Awọn mẹrẹẹrin ni wọn gba pe awọn jẹbi nigba ti akọwe kootu ka ẹsun jibiti ti wọn fi kan wọn ni kootu si wọn leti.
Eyi lo mu ki awọn agbẹjọro ajọ EFCC rọ adajọ lati jẹ awọn olujẹjọ naa niya lai fakoko ṣofo.
N lonidaajọ Adeyẹmi ba sọ gbogbo wọn sẹwọn ni ibamu pẹlu bi jibiti kaluku wọn ṣe lagbara to.
Adajọ sọ Adekanbi sẹwọn oṣu mẹfa, o ni ki Agoba ati Ogbonna ni tiwọn lọọ ṣe faaji oṣu marun-un pere lẹwọn, nigba to fi taanu-taanu sọ Oyetunji ni tiẹ sẹwọn oṣu kan ṣoṣo.
Yatọ si pe wọn yoo ṣẹwọn, ile-ẹjọ tun pa awọn onijibiti yii laṣẹ lati da owo ti wọn fọgbọn jibiti gba lọwọ awọn ẹni-ẹlẹni pada fun wọn.
Bakan naa lo gbẹsẹ le ẹrọ ibanisọrọ wọn, o ni ki foonu gbogbo wọn di dukia ijọba apapọ ilẹ yii porogodo.