Adajọ sọ fun Oluwoo: O ko lagbara lati yọ Ọtun Ajanasi nipo 

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Adajọ ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun to wa niluu Ikirun, Onidaajọ A. L. Adegoke, ti dajọ pe Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Adewale Akanbi, ko lagbara lati yọ Ajanasi ilu naa, Shayk Khalifa Asiru Adio Imran, kuro nipo rẹ.

A oo ranti pe ọjọ kẹrin, oṣu kẹfa, ọdun 2019, ni Oluwoo kede pe oun ti yọ Shayk Adio ni ipo Ajanasi ilu Iwo, ati pe ko gbọdọ kirun ni mọṣalaaṣi apapọ ati Yidi mọ, o ni ṣe lawọn ọlọpaa yoo gbe e lọjọkọjọ to ba wa sibẹ.

Ọrọ yii da awuyewuye pupọ silẹ nitori kia ni Oluwoo kede orukọ ẹni ti yoo gba ipo naa lọwọ Adio, idi si niyẹn to fi mori le ile-ẹjọ, to si fi ẹsun titẹ ẹtọ ọmọniyan lojumọlẹ kan Oluwoo atawọn yooku.

Eeyan mẹfa ni Shayk Adio pe lẹjọ, awọn naa si ni Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Ọba Adewale Akanbi, Shayk Hasim Ẹjalonibu, Oloye Abiọla Ogundokun, Alhaji Jimoh Alake ati Barisita Tawfeeq Ishola Tewogbade.

Agbẹjọro Isiaka Salimon lo ṣoju fun olupẹjọ, Agbẹjọro S. A. Tadeṣe ṣoju fun olujẹjọ kẹfa, iyẹn Tẹwọgbade, nigba ti ko si agbẹjọro kankan to ṣoju fun awọn olujẹjọ yooku ni kootu lọjọ idajọ.

Nigba to n ka idajọ rẹ, Onidaajọ Adegoke sọ pe ẹbẹ mẹta ni olupẹjọ gbe wa siwaju ile-ẹjọ, ikinni si ni lati kede pe awọn olujẹjọ mẹfẹẹfa ko lagbara labẹ ofin lati sọ pe olupẹjọ ko le jọsin tabi ṣe ẹsin Musulumi rẹ nibikibi to ba wu u tabi lati da a duro.

Ekeji ni pe ki ile-ẹjọ kede pe bi Oluwoo ṣe yọ Adio, to si sọ pe ko gbọdọ kirun ni mọṣalaasi apapọ ati Yidi mọ ko tọna rara, o si jẹ titẹ ẹtọ ọmọniyan loju mọlẹ gẹgẹ bo ṣe wa ninu abala ikẹrinlelọgbọn, ikarundinlogoji ati ikejidinlogun ofin orileede yii ti ọdun 1999.

Ibeere kẹta ni pe ki ile-ẹjọ paṣẹ pe Oluwoo atawọn olujẹjọ marun un to ku ko gbọdọ di olupẹjọ lọwọ, da a duro tabi de e lọna lati ṣe ojuṣe rẹ ni mọṣalaaṣi apapọ ilu Iwo, nipinlẹ Ọṣun tabi nibikibi lorileede yii.

Onidajọ Adegoke sọ siwaju pe olujẹjọ kin in ni, ikẹrin ati ikarun-un ko farahan ni kootu titi ti ẹjọ fi pari, eleyii to tumọ si pe wọn ko ta ko gbogbo ohun ti olupẹjọ n beere.

Nitori idi eyi, adajọ sọ pe niwọn igba ti gbogbo awọn olujẹjọ ti mọ pe ofin ilẹ wa faaye gba gbogbo eeyan lati ṣe ẹsin rẹ nibikibi, ẹnikẹni ko gbọdọ di olupẹjọ lọwọ tabi de e lọna lati jọsin ni mọṣalaaṣi apapọ tabi Yidi, eyi ti i ṣe ibeere ikinni ati ikeji.

Niwọn igba ti ile-ẹjọ ti gba ibeere meji akọkọ wọle, Onidaajọ Adegoke sọ pe oun tun fọwọ si ibeere kẹta fun olujẹjọ nitori ẹtọ rẹ ni labẹ ofin.

 

Leave a Reply