Adajọ ti gba beeli awakọ to pa Tolulọpẹ Arotile

Lẹyin ti ile-ẹjọ gba beeli ọmọkunrin to wa mọto, ati ẹni to ni mọto to pa Tolulọpẹ Arotile, ọmọbinrin afi-baalu- jagun akọkọ ni Naijiria ti wọn fi mọto kọ lu, to si gbabẹ ku ni ọjọ kẹrinla, oṣu keje, ọdun yii, Adajọ Emmanuel Hassan Benjamin ti sun ẹjọ naa si ọjọ kẹrinlelogun ati ikẹẹẹdọgbọn, oṣu yii.

Awọn tẹgbọn-taburo naa, Nehemiah ati David Adejọ, ni adajọ ile-ẹjọ kan ni Kaduna fẹsun kan ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Ẹsun meji ni wọn fi kan Nehemiah, o wa mọto lọna ti ko bofin mu, bẹẹ ni ko ni iwe aṣẹ, iyẹn lansẹnsi, lati wa mọto ọhun. Ko si tun gbaṣẹ lọwọ ẹni to ni mọto ko too wa mọto ọhun lọjọ kẹrinla,  yii, eyi to ṣeku pa Tolulọpẹ Arotile ninu ọgba awọn ologun, niluu Kaduna.

 Ṣugbọn awọn mejeeji ni awọn ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn yii.

Awọn ẹsun yii ni agbefọba, Martins Leo, ni o ta ko ofin irinna ti ipinlẹ Kaduna n lo, o si ni ijiya labẹ ofin to de irinna ọkọ nipinlẹ  Kaduna. Ọkunrin naa ni niwọn igba to jẹ pe ẹsun ti wọn fi kan awọn olujẹjọ ni i ṣe pẹlu ipaniyan ati aibikita pẹlu aikiyesara, niṣe ni ki adajọ paṣẹ pe ki wọn da Nehemiah pada si atimọle titi ti iwadii ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an yoo fi pari.

Ẹsun kan ṣoṣo ti wọn fi kan David to ni mọto naa ni tiẹ ni pe ko kiyesara, leyii to mu ko fa ewu fun ẹmi eeyan ati dukia.

Agbẹjọro fun awọn olujẹjọ, Ibrahim Omachi, bẹbẹ pe ki adajọ gba beeli awọn  olujẹjọ. O ni yatọ si pe wọn ko ṣẹ iru ẹṣẹ bẹẹ ri, o ti le lọsẹ mẹrin ti wọn ti wa latimọle.

Lẹyin ti Adajọ-agba Benjamin Hassan ti ile-ẹjọ giga naa gbọ alaye agbẹjọro olujẹjọ, o gba ẹbẹ agbẹjọro wọn, o si fun wọn ni beeli miliọnu kan naira ati oniduuro meji to n gbe lagbegbe ile-ẹjọ naa, ti wọn si ni nọmba idanimọ ti wọn fi le ṣewadii nipa wọn, iyẹn (BVN).

Lẹyin naa lo sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kẹrinlelogun ati ikẹẹẹdọgbọn oṣu yii.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹrinla, oṣu keje, ọdun yii, ni awọn ọmọkunrin naa wa mọto niwakuwa ninu ọgba ileeṣẹ ologun to wa ni Kaduna, leyii ti wọn fi ṣeku pa Tolulọpẹ Arotile, ọmọbinrin akọkọ ti yoo waa baalu ijagun agbera-paa nilẹ wa.

Wọn ni awọn fẹẹ ki ọmọbinrin naa ni wọn fi pada sẹyin, ti wọn si fi mọto gba a, to fi ori ṣeṣe, to si ku loju ẹsẹ.

Latigba naa ni wọn ti ti awọn ọmọkunrin to wa mọto naa atawọn ẹgbẹ rẹ ti wọn jọ wa nibẹ mọle, ko too di pe wọn gbe wọn lọ sile-ẹjọ ni Ọjọruu, ọsẹ yii.

 

 

5 thoughts on “Adajọ ti gba beeli awakọ to pa Tolulọpẹ Arotile

  1. Iku to TOLULOPE kiss oju lasan eni towa oko ati eni toni oko kiwon oju anu wo won biwon kolu TOLULOPE biwon o kolu awon tiwon pari re ti se pari eni wa oko won se sababi ni sungbon ohun to pamo oju olorun to ki oluwa Te TOLULOPE si afefe rere.

  2. Se kii SE PE ejo ORO yii lowo ninu, ejo apaniyan ati wiwa Oko laini iwe eri SE waa di PE won n gba beeli won,to baa ya a o ni gbo NKANKAN Lori ejo yii Mo.

Leave a Reply