Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni Onidaajọ Mahmud Abdulgafar tile-ẹjọ giga kan niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, sọ Aafaa ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan, Jamiu Isiaka, sẹwọn ọdun mejidinlọgbọn fẹsun pe o n fi orukọ Oludamọran pataki si Aarẹ Muhammed Buhari, Fẹmi Adeṣina, lu awọn oyinbo Korea ni jibiti lori ẹrọ ayelujara.
Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, EFCC, lo wọ Jamiu Isiaka lọ siwaju Onidaajọ Mahmud Abdulgafar, fẹsun pe o fi orukọ Adeṣina ati orukọ adari agba ajọ NNPC tẹlẹ, Maikanti Baru, lu oyinbo South Korean, kan Keun Sig Kim, ní jibiti owo to to ẹgbẹrun lọna ọgbọn miliọnu naira ninu oṣu kẹfa, ọdun 2019, niluu Ilọrin. O dibọn pe oun ni Fẹmi Adeṣina, o si ni oun fẹẹ ta epo fun un ni orile-ede Naijiria pẹlu iwe aṣẹ ileeṣẹ epo rọbi ni ilẹ yii, NNPC.
Olujẹjọ naa gba pe loootọ loun jẹbi ẹsun ti ajọ naa fi kan an, o ni oun fi owo naa ṣe oogun fun oyinbo ọhun ni, oun ra ẹyẹ igun, awọ erin, ẹdọ erin, ori ẹkun ati ẹdọ rẹ, gẹgẹ bii eroja etutu ọhun.
B Akinṣọla to jẹ aṣoju ajọ EFCC lo ko awọn ẹlẹrii meji siwaju ile-ẹjọ, ti Dare Folarin jẹ ọkan lara wọn lati fidi otitọ mulẹ pẹlu oniruuru ẹri to daju.
Onidaajọ Abdulgafar ni lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii ati awọn ẹri ti olupẹjọ ko siwaju ile-ẹjọ, o han pe loootọ ni olujẹjọ naa jẹbi ẹsun jibiti ti wọn fi kan an, fun idi eyi, ki Isiaka lọọ ṣẹwọn ọdun mejidinlọgbọn ni ọgba ẹwọn Mandala. Bakan naa ladajọ tun ni ki gbogbo awọn dukia to ko jọ lọna eru di tijọba apapọ.