Adajọ ti ju Adebọwale ọlọkada to fipa ba ọmọ ọdun mẹtala sun n’Ileefẹ sẹwọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Ileefẹ, ti ju Adebọwale Gboye, ẹni ọgbọn ọdun, sẹwọn lori ẹsun pe o fipa ba ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹtala lo po.

Aago mẹrin irọlẹ ọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje, ọdun yii, ni Adebọwale ki ọmọ naa mọlẹ lagbegbe Ọgbọn-Agbara, niluu Ileefẹ, to si ba a sun karakara.

Agbefọba to n ṣe ẹjọ naa, Emmanuel Abdullahi, sọ pe ṣe ni Adebọwale fọgbọn tan ọmọbinrin naa kuro lọdọ awọn obi rẹ, to si huwa buburu naa si i.

Abdullahi ni olujẹjọ jẹbi ẹsun meji; jiji ọmọ gbe ati fifi ipa ba ọmọdebinrin lo pọ, ṣugbọn o sọ pe oun ko jẹbi ẹsun mejeeji.

Agbẹjọro olujẹjọ, Ọgbẹni E. F. Adeọjọ bẹ kootu pe ko faaye beeli silẹ fun un, pẹlu ileri pe ko ni sa lọ fun igbẹjọ.

Adajọ A.A. Ayẹni ni oun ko le fun Adebọwale ni beeli, o paṣẹ pe ki wọn lọọ fi i pamọ sọgba ẹwọn ilu Ileefẹ lati le jẹ ẹkọ fun awọn miiran ti wọn ba fẹẹ huwa naa.

Adajọ ni ki Adebọwale wa nibẹ titi di ọjọ kẹtala, oṣu kẹjọ, ọdun yii, tile-ẹjọ yoo sọrọ nipa beeli rẹ.

Leave a Reply