Adajọ ti ju Ojuawo to pa ọmọ ẹgbẹ APC lọjọ idibo abẹle sẹwọn

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ile-ẹjọ Majisitreeti kan to wa niluu Ado-Ekiti ti paṣẹ pe ki ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogoji kan, Akintunde Ojuawo, lọọ maa gbatẹgun lọgba ẹwọn to wa ni Ado-Ekiti.

Ojuawo lawọn ọlọpaa gbe wa sile-ẹjọ pe oun lo pa Rotimi Ọlajide, ọmọ ẹgbẹ APC to ku lọjọ idibo abẹle ẹgbẹ naa l’Ekiti, ni Satide to kọja.

Agbefọba, Insipẹkitọ Bamigbade Olumide, ṣalaye ni kootu pe Ojuawo lo ṣeku pa ọmọkunrin naa ni ọgbọnjọ, oṣu keje, ọdun yii, ni agbegbe Fajuyi, Ado-Ekiti.

Olumide ni iwa ti ọmọkunrin yii hu lodi sofin iwa ọdaran ti ọdun 2012 ti ipinlẹ Ekiti n lo.

Onidaajọ Olubunmi Bamidele ko fakoko ṣofo to fi ni ki wọn maa gbe ọmọkunrin naa lọ si ọgba ẹwọn titi ti igbẹjọ mi-in yoo fi waye ni ọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan-an, ọdun 2021 yii.

Leave a Reply