Adajọ ti ju Sifu-difẹnsi to fipa ba ọmọ ọdun mẹtala lo pọ l’Ekiti sẹwọn

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ile-ẹjọ Majisreeti kan to wa l’Ado-Ekiti, ti paṣẹ pe ki ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan, Adebayọ Olukayode, to jẹ ọmọ ajọ sifu-difẹnsi l’Ekiti maa lọọ gba atẹgun lọgba ẹwọn titi di oṣu to n bọ.

Ọkunrin yii lawọn ọlọpaa gbe wa sile-ẹjọ pẹlu ẹsun pe o fipa ba ọmọ ọdun mẹtala lo pọ lọjọ ọdun Keresimesi ni Ado-Ekiti.

Olukayọde to n ṣiṣẹ pẹlu ẹka kogberegbe ninu ajọ naa nipinlẹ Ekiti lawọn ọlọpaa sọ pe o fọgban tan ọmọde yii wọnu ile akọku kan laduugbo naa, to si fipa ba a lo pọ.

Agbefọba nile-ẹjọ naa, Ọgbẹni Surdiq Adeniyi, ṣalaye pe afurasi ọdaran naa ṣẹ ẹsẹ yii laduugbo Peace Avenue, lọna to lọ lati ilu Ado-Ekiti si Afao, laaarọ ọjọ ọdun Keresimesi.

Ninu awijare tirẹ ni tesan, ọmọdebinrin to jẹ akẹkọọ ileewe girama kan ni Ado-Ekiti, sọ pe iya oun lo ran oun niṣẹ laaarọ ọjọ ọdun pe ki oun lọọ gbe ọgẹdẹ wa ni ṣọọbu. O ni nigba toun n bọ lọna loun ri ọkunrin sifu-difẹnsi yii pẹlu ọkada rẹ, to si sọ pe oun maa gbe oun de ibi toun n lọ.

Ọmọdebinrin yii sọ pe ọkunrin yii gbe oun lọ sile akọku kan ni adugbo naa, nibi to ti fi tipa ba oun ni ajọṣepọ.

O fi kun un pe ariwo ti oun pa ni awọn araadugbo naa gbọ ti wọn fi waa ba oun nile akọku yii lẹyin ti ọkunrin naa fi oun silẹ ninu ile naa.

Ẹsun yii ni agbefọba juwe gẹgẹ bii ohun to lodi sofin ifipa ba obinrin lo pọ ti ipinlẹ Ekiti ti wọn kọ lọdun 2012.

Adeniyi ti kọkọ tọrọ aaye pe ki ile-ẹjọ fun oun laaye lati le ko awon ẹlẹrii oun jọ, ati ki oun le gbe faili ẹjọ naa ranṣẹ si ẹka to n gba ile-ẹjọ nimọran, o ni igbesẹ yii yoo faaye silẹ lati gba esi lọdọ wọn ki igbẹjọ mi-in too waye.

Onidaajọ Mojisọla Salau paṣẹ pe ki ọdaran naa maa lọ si ọgba ẹwọn.

O waa sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kẹwaa, oṣu keji, ọdun 2022.

Leave a Reply