Adajọ ti ni ki Tunde lọọ ṣe ọdun Keresi lọgba ẹwọn, ṣọọsi lo ti lọọ jale l’Ọfatẹdo

Florence Babasola,Oṣogbo

Adeniyi Tunde, ẹni ọdun mejilelọgbọn, ladajọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo ti sọ pe ko wa lọgba ẹwọn ilu Ileṣa titi di ọjọ kẹjọ, oṣu kin-in-ni, ọdun to n bọ, tigbẹjọ yoo tun waye lori ẹsun ole jija ti wọn fi kan an.

Agbefọba to gbe Tunde wa si kootu, ASP Taiwo Adegoke, sọ fun adajọ pe laago meji oru ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kọkanla, ọdun yii, ni olujẹjọ atawọn kan ti wọn ti sa lọ bayii huwa buburu naa.

Ṣe ni wọn lọ si Christ Altar of Mercy Evangelical Ministry, nidojukọ ẸbunOluwa International School, to wa ni Ọfatẹdo, niluu Ido-Ọṣun, wọn si ji awọn ohun-eelo orin ti owo wọn le ni miliọnu kan naira (#1,050,000).

O ni iwa naa lodi, o si nijiya labẹ ipin okoolenirinwo o din mẹrin (416) ati irinwo o din mẹwaa (390) abala ikẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran ti ọdun 2002 tipinlẹ Ọṣun n lo.

Ṣugbọn olujẹjọ sọ pe oun ko jẹbi ẹsun mejeeji ti wọn fi kan an, bẹẹ ni agbẹjọro rẹ, Kazeem Adepọju, beere fun beeli rẹ lọna irọrun. Nigba yẹn ni agbefọba ta ko arọwa naa, o ni iwa jiji nnkan ninu ṣọọṣi ti n gbilẹ nipinlẹ Ọṣun bayii.

Idi si niyi ti Adajọ Oluṣẹgun Ayilara, fi ju u sẹwọn titi di ọdun to n bọ.

Leave a Reply