Adajọ ti ni ki wọn ju akẹkọọ Fasiti Ilọrin to lu tiṣa rẹ sẹwọn

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Yoruba ni ẹlẹṣẹ kan ki i lọ lai jiya, Adajọ Muhammed Ibrahim, tile-ẹjọ Majisteeti kan niluu Ilọrin, ti paṣẹ pe ki wọn fi akẹkọọ Fasiti Ilọrin, Salaudeen Waliu, ti inagijẹ rẹ n jẹ Captain Walz, to lu tiṣa rẹ, Arabinrin  Rahmat Zakariyat, si ọgba ẹwọn to wa niluu Ilọrin, fun iwa kotọ to hu ọhun.

Tẹ o ba gbagbe, Salaudeen Waliu, ti inagijẹ rẹ n jẹ Captain Walz, lo lu olukọ rẹ, Arabinrin Zakariyau, to si sọ pe idi toun fi lu u bii aṣọ ofi ni pe o ni koun waa lo ọdun kan si i nileewe tori oun ko ṣe SIWESI. Iwadii awọn agbofinro fi han pe akẹkọọ naa lo egboogi oloro lo jẹ ko lu olukọ ọhun, wọn ni bo ṣe de ọfiisi Arabinrin yii lo bẹrẹ si i gba teburu rẹ, to si n pariwo pe dandan ni ki olukọ naa fun oun ni maaki SIWESI, ti ko ṣe, nigba ti tiṣa kọ lati fun un ni maaki ọfẹ lo ba lu u lalubami.

Adajọ Muhammed Ibrahim to n gbẹjọ akẹkọọ naa ti waa paṣẹ pe ki wọn taari ẹ sọgba ẹwọn Mandela, o si sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun yii.

Leave a Reply