Adajọ ti ni ki wọn yẹgi fawọn Fulani tọwọ tẹ lori iku ọmọ Baba Faṣọranti

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Adajọ Ile-ẹjọ giga keje to wa l’Akurẹ, Onidaajọ Williams Ọlamide, ti dajọ iku fun mẹta ninu awọn ọdaran tọwọ tẹ lori ọrọ iku Funkẹ Arakunrin, ọmọ Oloye Reuben Faṣọranti, ti awọn agbebọn kan yinbọn pa loju ọna Marosẹ Ọrẹ si Ijẹbu-Ode, lọjọ kejila, ọsu Kẹje, ọdun 2019, lẹni ọdun mejidinlọgọta.

Ko pẹ rara sigba tiṣẹlẹ yii waye tọwọ awọn agbofinro fi tẹ awọn mẹrin, Muhammed Shehu Usman, Mazaje Lawal, Adamu Adamu ti inagijẹ rẹ n jẹ Chairman ati Auwalu Abubakar lori ẹsun pe wọn mọ nipa iku Oloogbe ọhun.

Mẹta ninu awọn odaran ọhun, Muhammed Shehu Usman, Mazaje Lawal ati Adamu Adamu ni wọn fẹsun mẹjọ ọtọọtọ kan lasiko igbẹjọ.

Lara ẹsun ti wọn fi kan wọn ni, igbimọ pọ huwa to lodi sofin, ipaniyan, ijinigbe, idigunjale, iditẹ atawọn ẹsun mi-in, ṣugbọn to jẹ pe ẹsun kan ṣoṣo, siṣe onigbọwọ fun awọn ọdaran ni wọn fi kan Auwalu to jẹ ẹni kẹrin wọn.

Agbẹjọro fun ijọba ipinlẹ Ondo, Amofin Charles Titiloye ni gbogbo ẹsun ti wọn fi kan awọn olujẹjọ naa lo ta ko iwe ofin ipinlẹ Ondo ati ti orilẹ-ede Naijiria.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ lẹyin ọpọlọpọ atotonu lati ẹnu kọmiṣanna feto idajọ nipinlẹ Ondo to tun jẹ agbefọba ati Amofin Ọbafẹmi Bawa to jẹ agbẹnusọ fawọn olujẹjọ, Onidaajọ Ọlamide ni gbogbo ẹri ti wọn fi siwaju ile-ẹjọ lo fidi rẹ mulẹ pe awọn Muhammed Shehu Usman, Mazaje Lawal ati Adamu Adamu jẹbi awọn ẹsun mẹsẹẹsan-an ti wọn fi kan wọn.

Adajọ ni awọn ọdaran mẹtẹẹta gbọdọ lọọ fẹwọn ọdun meje meje jura lori jijẹbi ẹsun kin-in-ni, ikẹta, ẹkarun-un ati ekeje, o ni oun fi wọn sẹwọn gbere lori ẹsun kẹfa eyi to ni i ṣe pẹlu idigunjale ati ṣiṣe amulo awọn nnkan ija oloro.

Lẹyin naa lo waa pasẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun wọn titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn lori jijẹbi ẹsun ipaniyan eyi ti i ṣe ẹsun keji ati ikẹjọ ti wọn fi kan wọn.

Ẹni kẹrin wọn, Auwalu, ladajọ ni ko maa lọ sile rẹ layọ ati alaafia pẹlu bo ṣe juwe ẹsun ti wọn fi kan an bii eyi ti ko lẹsẹ nilẹ.
Amofin Bawa to jẹ agbejoro ti ni o ṣee ṣe ki awọn si pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lẹyin ti awọn ba ṣe ayẹwo iwe idajọ naa daadaa.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: