Adajọ ti ni ki wọn yẹgi fun Ebenezer to pa aburo ẹ l’Ado-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ile-ẹjọ giga to wa l’Ado-Ekiti ti paṣẹ pe ki wọn yẹgi fun ọmọdekunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, Ọlọrunleke Ebenezer, titi ti ẹmi yoo fi bọ lẹnu rẹ. Ẹsun pe o pa aburo rẹ ni won fi kan an.

Agbefọba ile-ẹjọ naa, Ọgbẹni Gbemiga Adaramọla, sọ lasiko igbẹjọ naa pe ẹlẹrii marun-un lo mu iwe ti ọdaran fi jẹwọ pe loootọ loun ṣẹ ẹsẹ naa silẹ, ati fọto oku ọdaran naa, bakan naa lo tun mu esi abajade ile-iwosan iku oloogbe naa silẹ.

Ọdaran naa ni wọn lo jẹbi ẹsun mẹtẹẹta ti wọn fi kan an, ti ile-ẹjọ si paṣẹ pe ki wọn lọọ so o rọ titi ti ẹmi yoo fi bọ lẹnu rẹ.

Ọlọrunleke Ebenezer to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Kogi, nijọba ibilẹ Yàgbà, ni oun ati awọn miiran ti awọn ọlọpaa ṣi n wa ni sọ pe wọn gbimọ-pọ lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun 2019, lagbegbe ile Kọ̀kó, niluu Ado-Ekiti, ni wọn gbimọ-pọ, ti wọn si pa aburo rẹ, Olorunleke Sunday, ti wọn si gba ọkada Bajaj rẹ.

Ọlọrunleke Sunday to ni ọkada naa ti nọmba idanimọ rẹ jẹ ADK 100 UJ ni wọn sọ pe ẹgbọn rẹ Ebenezer, pa to si gba owo to to bii ẹgbẹrun lọna ogoji naira, lẹyin to fi ọbẹ oloju meji gun un pa.

Ọkan lara awọn to jẹrii nile-ẹjọ nigba ti igbẹjọ naa n lọ lọwọ, sọ pe oun ji lọ sile ọdaran naa laaarọ ọjọ ọhun lati fi iku aburo rẹ to o leti. O ni ọdaran naa sọ foun pe awọn adigunjale lo kọ lu u, eyi lo jẹ ki oun fura pe ọdaran naa mọ nipa iku aburo rẹ yii.

O ṣalaye pe ohun ti oun ri yii lo jẹ ki oun lọọ fọrọ naa to wọn leti ni teṣan Ọlọgẹdẹ, Lasiko  itọpinpin lawọn ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe ọdaran yii gan-an lo pa aburo rẹ, to si tun ko gbogbo dukia rẹ ki awọn ọlọpaa to lọ mu un ni Akurẹ to fara pamọ si.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajo Bamidele Ọmọtọṣọ sọ pe agbefọba ti sa gbogbo ipa rẹ lati le fi idi ọrọ rẹ mulẹ ṣinṣin nile-ẹjọ yii, o si tun fi idi ẹsun igbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi, idigunjale ati ipaniyan ti wọn fi kan Ebenezer mulẹ ṣinṣin pẹlu ẹri to daju.

Leave a Reply