Adajọ ti ran fẹmi lẹwọn, agbero to lọọ ji foonu awọn erọ ọkọ l’Ado-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ẹwọn ọdun meji aabọ gbako ni ile-ẹjọ Majisreeti ipinlẹ Ekiti ju ọkunrin agbero kan, Fẹmi Ayelegun, si bayii, nitori pe o ji foonu meji to jẹ ti awọn ero to waa wọ mọto, to si tun lu ọkan lara awọn ero naa bii ko ku.

Agbegbe Oke-Iyinmi, niluu Ado-Ekiti, ni Fẹmi ti n ṣiṣẹ agbero, gẹgẹ bi Agbefọba Oriyọmi Akinwale ṣe wi. O ṣalaye pe olujẹjọ ṣẹ ẹṣẹ yii ni deede aago mẹrin irọlẹ ọjọ keje, oṣu kẹjọ, to kọja yii.

Akinwale sọ pe olujẹjọ ji foonu kan ti iye owo rẹ jẹ ẹgbẹrun mẹrindinlogoji naira (37,000) eyi ti i ṣe ti  Pelemọ Oluwaṣẹsan. O ni lẹyin to gba foonu naa tan, o tun lu ẹni to ni foonu bii ẹni lu bara ni.

O fi kun un pe lọjọ yii kan naa ni Fẹmi tun ji foonu mi-in ti iye owo rẹ jẹ ẹgbẹrun marun-un naira, eyi ti i ṣe ti Ọgbẹni Ibrahim Muhammed.

Agbefọba sọ pe iwa ti Fẹmi Ayelegun hu yii lodi siwee ofin ipinlẹ Ekiti, ijiya si wa fun un.

Ninu awọn iwe to ko wa si kootu lati gbe ọrọ rẹ lẹsẹ ni iwe ti olujẹjọ kọ ni teṣan ọlọpaa wa, nibi ti Fẹmi ti jẹwọ pe loootọ loun huwa ti wọn mu oun fun, agbefọba si fi gbogbo ẹ han kootu.

Olujẹjọ paapaa loun gba pe oun jẹbi ẹsun tile-ẹjọ fi kan oun naa, o ni kijọba ṣiju aanu wo oun, oun ko ni i ṣe bẹẹ mọ.

Adajọ Moses Faola lo gbọ ẹjọ naa, o si paṣẹ pe ki Fẹmi lọọ ṣẹwọn ọdun meji fun ti foonu akọkọ to ji, tabi ko san ẹgbẹrun mẹwaa naira owo itanran.

Fun foonu ẹlẹgbẹrun marun-un naira to ji, Adajọ paṣẹ pe ki Fẹmi lọọ ṣẹwọn oṣu mẹfa, tabi ko sanwo itanran ti i ṣe ẹgbẹrun mẹta naira.

Ṣugbọn ọkunrin agbero yii ko ri owo kankan san ninu mejeeji, idi si niyẹn ti wọn fi gbe e lọ sọgba ẹwọn, nibi ti yoo ti faṣọ penpe roko ọba.

Leave a Reply