Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Ekiti, ti paṣẹ pe ki ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogoji kan, Enouch Gbinyiam, to tun jẹ pasitọ ijọ Winners (Living Faith Church), ni Omuo-Ekiti, maa lọ sẹwọn gbere. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o fipa ba ọmọ ọdun mẹjọ to jẹ ọmọ ijọ rẹ. Ki ile-ẹjọ too ran an lẹwọn, oun lo wa lori ijọ (Winners Chapel), to wa ni Omuo-Ekiti, nijọba ibilẹ Ariwa, nipinlẹ Ekiti. Ẹsun ifipa ba ni lo pọ ni ile-ẹjọ fi kan an, eyi to mu ki Onidaajọ O. O. Ogunyẹmi paṣẹ pe ki o lọọ lo iyooku aye rẹ lọgba ẹwọn. Ọmọọdun mẹjọ naa to jẹ ọmọ ijọ Pasitọ Enock lo ki mọlẹ, to si fipa ba a lo pọ lakooko ti ọmọdebinrin naa wa sile-ijọsin naa fun eto adura. Gẹgẹ bi iwe ẹsun ti wọn fi kan ọdaran naa ṣe sọ, ọmọdebinrin naa maa n wa si ile pasitọ naa to wa lẹgbẹẹ ile ijọsin naa lati waa ba iyawo rẹ ṣiṣẹ ile, ati lati waa ba awọn ọmọ rẹ ṣiṣẹ amurele ti wọn ba fun wọn lati ileewe. Wọn ni lọjọ kan ti ọmọdebinrin naa wa sile wọn ni ọkunrin yii fi oogun oorun sinu ọti ẹlẹridodo, to si gbe e fun ọmọdebinrin yii mu, niyẹn ba sun lọ fọnfọn. Nigba to pada ji saye lo ri i pe ẹjẹ n jade lati oju ara oun. Iṣẹlẹ yii lo mu ki awọn obi ọmọ naa lọọ sọrọ ọhun fawọn ọlọpaa, ti wọn si mu pasitọ yii, ti wọn tun pada gbe e wa sile-ẹjọ pẹlu ẹsun ifipa ba ni lo pọ ati titẹ ẹtọ ọmọdebinrin mọlẹ to jẹ ofin ti wọn kọ lọdun 2019. Agbefọba, Ọgbẹni Julius Ajibare, pe ẹlẹrìí mẹrin lakooko igbẹjọ naa. Bakan naa lo mu iwe-ẹri ayẹwo ti wọn ṣe fun ọmọdebinrin naa nile-wosan gẹgẹ bii ẹsibiiti lati fi idi ẹjọ rẹ mulẹ. Pasitọ Enock to sọrọ lati ẹnu agbẹjọro rẹ, Ọgbẹni Adeyinka Ọpalẹkẹ, naa pe ẹlẹrii kan pere. Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Ogunyẹmi ṣalaye pe agbefọba naa fi ẹri to daju mulẹ pe loootọ ni pasitọ yii fipa ba ọmọdebinrin naa lo pọ. O waa paṣẹ pe ki ọkunrin naa lọọ lo iyooku aye rẹ lọgba ẹwọn.