Adajọ ti ran Suliman lẹwọn gbere, ọmọ bibi inu ẹ lo ṣe ‘kinni’ fun.

Ismail Adeẹyọ

Katikati lọrọ to n jade lẹnu baba ẹni ọdun mejilelogoji (42) kan, Suliman Usman, ti wọn wọ lọ si ile-ẹjọ lori ẹsun pe o fipa ba ọmọ bibi inu ẹ ti ko ju ọdun mẹjọ lọ lajọṣepọ.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọgbọnjọ, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, ni ọkunrin ti wọn fẹsun kan pe o fipa ja ibale ọmọ rẹ n kawọ pọnyin rojọ ni kootu to wa niluu Ikẹja, nipinlẹ Eko, niwaju Onidaajọ Rahman Oshodi.

Agbefọba pe awọn ẹlẹrii mẹrin lati fidi ọrọ rẹ mulẹ. Ninu awọn ẹlẹrii to pe ni iya ọmọ yii, Dokita to tọju rẹ pẹlu olukọ ọmọ ọdun mẹjọ yii. Wọn bi ọmọ naa leere pe bawo ni ọrọ ṣe jẹ, o si ṣalaye bi baba rẹ ṣe ja ibale rẹ, to si tun dunkooko mọ ọn pe ko gbọdọ sọ fun ẹnikankan. O fi kun ọrọ rẹ pe nigba ti oun ko mọ nnkan toun le ṣe loun ṣe fi ọrọ naa to olukọ oun leti.

Ninu ọrọ iya ọmọ yii, o ni oun kan ṣakiyesi pe ọmọ naa ko rin daadaa ni, loun ba lọ sọdọ olukọ rẹ lati beere pe ki lo fa a ti ọmọ naa ko ṣe rin daadaa mọ.

Olukọ ọmọ yii lo waa ṣalaye ohun ti akẹkọọ rẹ sọ fun un, o ni, “Ni kete ti mo gbọ ọrọ yii, ni mo sare gbe ọmọ mi lọ sọdọ dokita lati ṣayẹwo fun un, nibẹ ni wọn ti fidi rẹ mulẹ pe wọn ti sọ ọmọ naa di koronfo. Mo beere lọwọ baba rẹ, ṣugbọn ija nla lo gbe ko mi loju, ni mo ba pe awọn agbofinro lati ba mi beere lọwọ rẹ, ibẹ la si gba dele-ẹjọ”.

Ninu ọrọ ẹni ti wọn fẹsun kan, o kọkọ ni irọ ni iyawo oun n pa mọ oun, pe o kan fi ọrọ naa ba orukọ oun jẹ lasan ni, nigba to ya lo ba tun ni ki wọn foriji oun, pe iṣẹ eṣu ni.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Oshodi bi  Suliman Usman pe iru igbadun wo gan-an lo fẹẹ ri lara ọmọ bibi inu rẹ, ti ko ju ọmọ ọdun mẹjọ lọ. O fi kun un pe  eewọ ni ohun ti baale ile yii ṣe, o si koro leti jọjọ. Adajọ ni iwa ẹranko gbaa ni, o si gbọdọ gba idajọ ẹṣẹ to ṣẹ ọhun.

Lẹyin eyi lo paṣẹ pe ki wọn lọọ ju baba naa sọgba ẹwọn, ko lọọ lo eyi to ku ti yoo lo laye rẹ lọhun-un. O fi kun un pe ki wọn lọọ kọ orukọ rẹ sinu iwe awọn ọdaran a-fipa-ba-ni-lopọ, nipinlẹ Eko.

 

Leave a Reply