Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ile-ẹjọ giga kan to wa nipinle Ekiti, ti paṣẹ pe ki okunrin ẹni aadọta ọdun kan, Jimoh Dele, maa lọọ gbatẹgun lọgba ẹwọn fun ọdun mọkanlelogun. Ẹsun pe o ji irẹsi atawọn ounjẹ mi-in gbe ni wọn tori ẹ sọ ọ sẹwọn.
Dele ti gbogbo eeyan mọ si Dele Pẹtim, ni wọn fẹsun kan pe o lọọ fọ ileetaja kan to jẹ ti Arabinrin Adelẹyẹ Oluwayẹmisi, lagbegbe ile-epo Mobil, l’Ado-Ekiti, lọjọ kọkanla, ọṣun Karun-un, ọdun 2020, to si ko ounjẹ ati owo to le ni ẹgbẹrun lọna igba Naira (N234,000).
Ẹsun yi ni ile-ẹjọ juwe gẹgẹ bii eyi to lodi sofin ipinlẹ Ekiti ti wọn kọ lọdun 2012.
Ninu iwe ti wọn fi gba ohun rẹ silẹ ni tesan ọlọpaa lakooko itọpinpin, Arabinrin Oluwayẹmisi to ni ṣọọbu naa sọ pe igba meji otọọtọ ni wọn ti fọ ṣọọbu oun, ti wọn si ko ounjẹ bii irẹsi, ẹwa, tomato, sẹmo ati ọbẹ ti oun jẹ ku lọjọ naa.
Nigba to n sọrọ niwaju adajọ, Agbefọba, Sajẹnti Ọladele Ayọdeji, sọ pe ọwọ tẹ ọdaran naa lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2021, pẹlu ẹsun ijinigbe ati ipaniyan.
Ọladele ni ni kete ti ọwọ awọn tẹ ẹ, ti iwadii sì bẹrẹ lo jẹwọ pe oun loun fọ ṣọọbu Arabinrin Oluwayẹmisi ni agbegbe Ajilosun, ni Ado-Ekiti, ti oun si ko ounjẹ ati ọbẹ to ṣẹṣẹ se ni ọjọ yii.
Lati fi idi ẹjọ rẹ mulẹ ṣinṣin, agbefọba pe ẹlẹrii meji, o si tun gbe iwe ti wọn fi gba ohun rẹ silẹ lakooko itọpinpin awọn ọlọpaa siwaju adajọ. Bakan naa lo tun mu iwe ti wọn fi gba ohun silẹ lẹnu eni to ni ṣọọbu ti ọdaran naa lọọ fọ ati awọn ẹri miiran silẹ.
Agbẹjọro olujẹjọ, Ọgbẹni Tọpe Salami, ko ri ẹlẹrii kankan pe.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Ọlalekan Ọlatawura sọ pe agbefọba naa ti sa gbogbo ipa lati fi idi ẹjọ rẹ mulẹ, o fi kun un pe ọdaran naa jẹbi ẹsun ti won fi kan an.
O sọ ọ si ẹwọn ọdun mẹrinla fun ẹsun kin-in-ni, o si ran an ni ẹwọn ọdun jeje fun ẹsun keji pẹlu iṣẹ aṣekara.