Stephen Ajagbe, Ilọrin
Agunbanirọ kan, Sam Abiọla ati Adebiyi Sọdiq, ti ajọ EFCC wọ lọ sile-ẹjọ lọsẹ to kọja, niluu Ilọrin, fẹsun ṣiṣe jibiti ori ẹrọ ayelujara, ti dero ọgba ẹwọn bayii.
Adajọ Adenikẹ Akinpẹlu tile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara lo dajọ ẹwọn fun wọn l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Adenikẹ ni ki awọn mejeeji lọọ ṣẹwọn oṣu mẹfa tabi ki wọn sanwo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira fun ẹsun kọọkan.
Adajọ tun paṣẹ pe ijọba ti gbẹsẹ le awọn foonu ati ẹrọ kọmputa alaagbeka ti wọn n lo fun iṣẹ jibiti naa.
Lọjọ kin-in-ni, oṣu keji, ọdun yii, ni EFCC wọ awọn mejeeji lọ sile-ẹjọ fun ẹsun kan naa.
Ẹsun ti wọn fi kan Abiọla to n sinjọba nipinlẹ Kogi ni pe laarin oṣu keje si ikẹsan-an, ọdun 2019, o pe ara rẹ lobinrin lori intanẹẹti, o si lo ayederu orukọ oyinbo, Missie Bonie, ati nọmba foonu kan; +19287060683, lati fi tan ọkunrin oyinbo kan torukọ rẹ n jẹ, Rick, pe oun nifẹẹ rẹ, to si gba ọgọrun-un marun-un dọla lọwọ onitọhun.
Nigba tile-ẹjọ ka ẹsun rẹ si i leti, olujẹjọ naa loun jẹbi.
Bakan naa, Adebiyi Sọdiq to n pe ara rẹ ni ‘Maria Monica’ oyinbo alawọ funfun, ninu oṣu kẹjọ, ọdun 2020, lo ikanni gmail kan; terrellwhite856@gmail.com, lati maa fi gba owo lọwọ ẹnikan to n jẹ Manny.
Olujẹjọ ọhun naa gba pe loootọ loun jẹbi ẹsun naa.
Agbẹjọro ijọba, Ọgbẹni O.B Akinṣọla, pe ẹlẹrii kan to jẹ oṣiṣẹ ajọ EFCC, Ali Mohammed, siwaju ile-ẹjọ lati ṣalaye bi ẹjọ naa ṣe lọ.
Mohammed ṣalaye pe agbegbe ilu Ọffa lawọn ti mu awọn afurasi naa. O ni ẹnikan to forukọ bo ara rẹ laṣiiri lo kọwe sileeṣẹ awọn nipa ohun ti wọn n ṣe.
Ni tẹjọ Sọdiq, Agbefọba, Sẹsan Ọla, pe oṣiṣẹ EFCC, Eze Uchenna, lati ṣalaye bi ẹjọ naa ṣe jẹ. Iyẹn ko awọn ẹri to daju silẹ, eyi to fi han pe loootọ afurasi naa lọwọ ninu jibiti ori intanẹẹti.