Faith Adebọla, Eko
Ọpọ eeyan jankanjankan lagbo oṣelu ati ni ẹka eto idajọ, paapaa nipinlẹ Eko, lo ti n daro Oloogbe Adajọ Dọlapọ Akinsanya, ẹni to jade laye loru Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii.
Ẹni ọdun mọkandinlọgọrin (79) ni mama naa nigba ti iku fi pa oju rẹ de lẹyin aisan ranpẹ kan.
Lara awọn oloṣelu to daro oloogbe yii ni Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, o ni iru kaun-un ṣọwọ lawujọ okuta, akọni pataki lawujọ awọn adajọ ni adajọ-binrin yii, tori lasiko tijọba ologun gbegi dina fun eto ijoba demokresi nilẹ wa lobinrin yii gbe idajọ nla kalẹ lati gbeja eto iṣejọba awa-araawa.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹwaa, oṣu kọkanla ọdun 1993 ni Oloogbe Adajọ-binrin Akinsanya tile ẹjọ giga ijọba apapọ nigba naa gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ kan ti Oloye Moshood Kasimawo Abiọla pe tako ijọba fidi-hẹẹ ti ijọba ologun ajagun-fẹyinti Ibrahim Babangida gbe kalẹ.
Ninu idajọ naa lo ti kede pe ijọba fidi-hẹẹ ko bofinmu, ko lẹtọọ lati wa nipo, o si tipa bẹẹ yẹ aga mọ Oloye Ẹrnest Shonekan to jẹ olori ijọba fidi-hẹẹ naa nidi. O ni Babangida to buwọ lu ofin ti wọn fi ṣedasilẹ ijọba fidi-hẹẹ yii ko lagbara lati ṣe bẹẹ, tori o ti kuro lori aleefa lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹjọ, ki ijọba tuntun naa too yọju sita.
Ọpọ eeyan lo gboṣuba fun idajọ yii, ati ọkan akin tobinrin naa fi gbe idajọ naa kalẹ, laibẹru awọn ologun. Idajọ yii lo ṣokunfa bi Oloogbe Sani Abacha ṣe ko awọn ologun sodi, ti wọn si palẹ ijọba fidi-hẹẹ naa mọ, lalẹ ọjọ tidajọ naa waye gan-an.
Ọdun 1989 ni Akinsanya di adajọ, ọdun mẹtadinlogun lo si fi wa lori aga idajọ, lati kootu kan si omi-in, ko too fẹyin ti lọdun 2006.