Lẹyin ọjọ meloo kan ti ibo ipinlẹ Edo waye, nibi ti PDP ti wọle, ti ẹgbẹ oṣelu APC si fidirẹmi, Adams Oshimhole ti sọrọ o.
Ọkunrin oloṣelu naa ti sọ pe abajade ibo ọhun ko ba oun ninu jẹ rara gẹgẹ bi ọpọlọpọ eeyan ti ṣe lero, ṣugbọn niṣe loun gba pe ki i ṣe gbogbo idije naa leeyan maa n yege ninu ẹ.
Alaga ẹgbẹ oṣelu APC tẹlẹ yii tun fi kun un pe, oun ko ni i kaaarẹ ọkan lati maa wa bii ilọsiwaju yoo ṣe ba ijọba dẹmokiresi ni Naijiria.
Bakan naa ni Pasit̀ọ Ize-Iyamu, ẹni to dije lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC naa tun sọ le e, o loun ko ba oniroyin kankan sọrọ pe ki Godwin Obaseki pada sinu ẹgbẹ oṣelu APC.
O lo pẹ toun ti sọrọ naa, ki i ṣe lana-an ode yii bi wọn ti ṣe n gbe e kiri. Okunrin yii fi kun un pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP kan lo wa nidii ọrọ ọhun lati fi parọ mọ oun.
Ṣaaju asiko yii ni iroyin kan ti kọkọ gbalu wi pe Pasit̀ọ Ize-Iyamu n bẹ Gomina Godwin Obaseki pe ko pada sinu ẹgbẹ oṣelu APC, awọn ti ṣetan lati ṣiṣẹ pẹlu ẹ fun ilọsiwaju ipinlẹ naa.