Adamu lagi mọ ọlọkada lori n’Ibafo, lo ba gbe alupupu ẹ lọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bo tilẹ jẹ pe meji ni wọn, iyẹn awọn ọkunrin Hausa ti wọn gba ọkada Bajaj lọwọ ẹnikan n’Ibafo lọjọ Ẹti to kọja yii, ọkan ninu wọn torukọ ẹ n jẹ Muhammed Adamu lọwọ awọn fijilante VGN ipinlẹ Ogun ba, o si ti jẹwọ fun wọn pe igi loun ati ekeji oun to ti sa lọ bayii la mọ ọlọkada naa lori tawọn fi gbe maṣinni rẹ lọ.

Fijilante to fi iṣẹlẹ naa to ALAROYE leti, David Ọlatayọ, ṣalaye pe Yuniiti Ibafo lawọn wa toun fi ri awọn meji kan lori ọkada, ti wọn n wo yeleyele bii ole, ti irisi wọn si mu ifura dani. O ni iyẹn lawọn ṣe da wọn duro, ṣugbọn to jẹ niṣe ni wọn bẹrẹ si i sa lọ titi ti wọn fi wọnu igbo to wa nitosi.

Nibi ti wọn ti n le wọn lọ naa ni ọwọ ti ba Adamu pẹlu ọkada naa, bi wọn ṣe n mu un bọ ni wọn ri ọlọkada ti wọn gba maṣinni lọwọ ẹ tiyẹn n kigbe ole bọ pẹlu ori ẹ ti wọn lagi mọ.

Ọlọkada naa ṣalaye pe oun gbe awọn Mọla naa gẹgẹ bii ero ni, afi bawọn ṣe de ibi ti wọn pe foun ti wọn gbe ẹgbẹrun kan naira le oun lọwọ pe koun mu ṣenji wa, bẹẹ, idaji kutu ni,oun ko ni ṣenji, ko si sẹni to le ṣẹ oun lowo naa lasiko yẹn.

O ni nibi toun ti n sọ pe ko si ṣenji naa ni ọkan ninu awọn ọkunrin meji ọhun ti lagi mọ oun lori, bi wọn ṣe gbe oun ṣubu, ti wọn gbe ọkada oun lọ niyẹn.

Nigba to n ṣalaye ara ẹ, Adamu; ẹni ọdun mọkanlelogun, sọ pe ojule keji, Opopona Ọla, l’Ogijo, loun n gbe, ṣugbọn Ibafo nibi toun yan laayo fun jija ọkada gba.

O ni ekeji oun to sa lọ naa lọga oun ninu iṣẹ yii, oun naa loun si n wo lawokọṣe.

Ọdọ awọn ọlọpaa teṣan Ibafo ni Adamu wa lasiko ti a n kọ iroyin yii, nitori awọn fijilante ti fa a le wọn lọwọ. Ọsẹ yii ni wọn ni yoo foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply