Adedeji, ayederu lọọya, n lọ sẹwọn ọdun mẹta ba a ṣe kọwe rẹ l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

 Kootu ko fi ẹjọ ayederu lọọya kan, Adedeji Ebenezer, ẹni ti aṣiri ẹ tu lọjọ karun-un oṣu kẹjọ yii, falẹ rara, nigba ti yoo fi di ọjọ kejila, oṣu kan naa, ile-ẹjọ ti ran an lẹwọn ọdun mẹta gbako.

 Asiko ti lọọya naa n gba ẹjọ ẹlẹjọ kan ro ni kootu Majisireeti agba n’Itori, laṣiri tu pe ki i ṣe lọọya, ko tilẹ mọ nnkan kan nipa ofin, iṣesi rẹ paapaa ko jọ ti lọọya gidi.

Nigba ti ẹjọ naa kọkọ bẹrẹ niwaju Adajọ B.A Ṣomorin, Adedeji loun ko jẹbi. Ṣugbọn nigba ti wọn bẹrẹ si i da ibeere oriṣiiriṣii bo o, ti wọn n fi ẹri ti ko jọ ara wọn gbe e lẹsẹ pe olujẹjọ yii ki i ṣe lọọya tootọ, Adedeji jẹwọ pe oun ki i ṣe lọọya, ko sibi kan ti wọn ti foun niwee-ẹri amofin. O lohun toun yoo jẹ loun n wa toun fi n gba ẹjọ ro kiri, bẹẹ ko sẹni to fura soun ri ninu awọn onibaara oun, aṣiri oun ko si tu ri.

Nigba to ti jẹwọ lọrọ ko ti pariwo mọ, wọn gbe e lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Ewekoro. Nigba to di Ọjọruu, ọjọ kejila, oṣu kẹjọ yii, Adajọ Ṣomọrin naa lo gbọ ẹjọ Adedeji, ẹwọn ọdun mẹta gbako lai ni owo itanran ninu lo paṣẹ pe ki ọkunrin naa lọọ ṣe pẹlu iṣẹ aṣekara.

 

Leave a Reply