Adedoyin: Wọn ko yọ ohunkohun lara akẹkọọ Fasiti Ifẹ ti a hu oku rẹ jade-Ọlọpaa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, ti sọ pe ko si ootọ kankan ninu ahesọ to n lọ kaakiri pe wọn yọ awọn ẹya ara kan lara akẹkọọ Fasiti Ifẹ, Timothy Adegoke, nigba ti wọn hu oku rẹ jade n’Ileefẹ.

Lakooko ti Ọpalọla n kopa lori eto ori redio kan niluu Oṣogbo l’Ọjọbọ, Tọsidee, lo sọ pe awọn mọlẹbi ọmọkunrin naa pẹlu dokita to mọ nipa ẹya-ara ati kọmiṣanna ọlọpaa wa nibẹ nigba ti wọn n hu oku naa jade.

O ni ko si ẹya-ara rẹ kankan to din nigba ti wọn gbe e jade, o si rọ awọn araalu lati dẹkun gbigbe iroyin to le da wahala silẹ ninu ilu kaakiri.

Ọpalọla fi kun ọrọ rẹ pe nigba ti awọn bẹrẹ iwadii, ti awọn si ri i pe o wọle sinu otẹẹli Hilton yẹn, lawọn ko mẹfa lara awọn oṣiṣẹ ibẹ fun iwadii.

O ni nigba ti awọn tun tẹsiwaju ninu iwadii lawọn lọọ fi pampẹ ofin mu ẹni to ni otẹẹli naa, Dokita Ramon Adegoke Adesoyin, ẹni to ti wa lakata awọn lati ọjọ kẹẹẹdogun oṣu yii.

Ọpalọla fi kun ọrọ rẹ pe oku Timothy wa nileewosan, nibi ti wọn ti n ṣayẹwo ohun to pa a gan-an. O waa ke si awọn araalu lati fun awọn ọlọpaa lanfaani lati ṣiṣẹ iwadii wọn lori iṣẹlẹ naa.

A oo ranti pe akẹkọọ ẹka ti wọn ti n fimọ kun imọ (MBA) ni Fasiti OAU ni Timothy Adegoke, ọjọ keje, oṣu kọkanla yii, to gba yara ni otẹẹli Hilton, niluu Ileefẹ, lo di awati, ko too di pe awọn ọlọpaa hu oku rẹ lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii.

Leave a Reply