Adehun ti wa nilẹ pe Tinubu ni Buhari maa gbejọba fun- Hanga

Faith Adebọla

“Aṣiri to foju han ni, ki i ṣe ọrọ abumọ rara, adehun wa laarin wọn (Buhari ati Tinubu), pe ti Buhari ba ti ṣejọba tan, Tinubu lo maa gbejọba fun. Idi niyẹn ti Tinubu ko fi kuro ninu ẹgbẹ lẹyin ti Buhari ti ṣe saa kin-in-ni. Ti ki iba ṣe ti adehun yẹn ni, ipari saa kin-in-ni ti Buhari ṣe ni Tinubu iba ti fẹgbẹ APC silẹ.”

Alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu Congress for Progressive Change (CPC) nigba kan, Ọgbẹni Rufai Hanga, lo ṣiṣọ loju eegun ọrọ yii pe adehun ọlọrẹẹ-ṣọrẹẹ kan wa laarin Aarẹ Muhammadu Buhari ati agba oloṣelu ilu Eko nni, Aṣiwaju Bọla Tinubu, o ni adehun naa ni pe Tinubu ni Buhari maa gbejọba fun to ba ti pari saa meji rẹ tan nipo Aarẹ.

Ninu ọrọ kan to ba iweeroyin Daily Trust sọ, Rufai sọ pe “meji ladehun, adehun taarata ati adehun ti ki i ṣe taarata, oriṣii meji yii lo fidi mulẹ labẹ ofin. Loootọ ko sohun to le yẹ adehun taarata, sibẹ adehun wa laarin Buhari ati Tinubu, o si ti kuro lọrọ ma-jẹ-a-gbọ.”

Tẹ o ba gbagbe, ọkan pataki ni Buhari jẹ lẹgbẹ oṣelu CPC ọjọun, ẹẹmeji lo ti jade dupo aarẹ labẹ ẹgbẹ ọhun, ki ẹgbẹ naa ati ẹgbẹ Action Congress of Nigeria (ACN) ati All Nigeria People’s Party (ANPP) too para-pọ di ẹgbẹ All Progressive Congress (APC), eyi ti Buhari jawe olubori idibo sipo Aarẹ labẹ asia rẹ lọdun 2015.

Ṣe tipẹ ni awuyewuye ti n lọ nigboro pe Bọla Tinubu n palẹmọ lati dije dupo aarẹ ilẹ wa lọdun 2023, bẹẹ si lawọn posita lọkan-o-jọkan n lọ kaakiri nipa erongba naa, sibẹ, Tinubu funra ẹ ko ti i sọrọ nipa erongba ọhun, yatọ si bo ṣe n sọ pe oun ko mọ nipa awọn posita tawọn eeyan n lẹ, o ni awọn ololufẹ oun ni wọn wa nidii ẹ, ohun ti wọn n fẹ koun ṣe ni.

Leave a Reply