Adekunle Ajisebutu di Alukoro ọlọpaa Eko tuntun

Faith Adebọla, Eko

 Ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa nilẹ wa, IGP Usman Alkali Baba, ti yan Alukoro tuntun fun ileeṣẹ ọlọpaa Eko, CSP Adekunle Ajisebutu lo bọ sipo naa, bẹrẹ lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹfa, oṣu kẹjọ yii.

Ajisebutu yoo gbaṣẹ lọwọ CSP Olumuyiwa Adejọbi to ti wa nipo naa lati ọdun to kọja.

Ṣaaju iyasipo rẹ tuntun yii, Ajisebutu ni igbakeji ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Kọmandi Festac, nipinlẹ Eko, o si ti figbakan jẹ Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, laarin ọdun 2015 si 2019, o tun ṣiṣẹ Alukoro fun ẹka ọlọpaa Zone 11, l’Oṣogbo, nipinlẹ Ọṣun, igba kan si wa o jẹ Igbakeji Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun.

Nọmba foonu Alukoro tuntun naa ni 08036536581.

Atẹjade kan lati ọfiisi Alukoro ọlọpaa Eko to tẹ ALAROYE lọwọ fihan pe iṣẹ ti gbe Olumuyiwa Adejọbi lọ si ẹka Alukoro apapọ, lọfiisi ọga agba patapata niluu Abuja, olu-ilu ilẹ wa.

Leave a Reply