Adekunle yoo ṣẹwọn oṣu mẹfa l’Abẹokuta, ole lo ja ni ṣọọbu meji

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọgba ẹwọn to wa ni Ọ̀bà, l’Abẹokuta, ni ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn kan, Adekunle Emmanuel, wa bayii, ile-ẹjọ Majisreeti to wa n’Iṣabọ lo paṣẹ ẹwọn oṣu mẹfa fun un l’Ọjọruu to kọja, lẹyin to jẹwọ pe oun fọ awọn ṣọọbu meji lọdun to kọja, oun si ji ẹru to le lẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira ko ninu awọn ṣọọbu naa niluu Abẹokuta.

Agbefọba lori ẹjọ naa, Inspẹkitọ Lawrence Olu-Balogun, sọ fun kootu pe lọjọ kejila, oṣu keji, ọdun 2019, laago mẹfa aarọ, loju ọna LCD, Panṣẹkẹ, Abẹokuta, Adekunle gba oju windo wọ ṣọọbu obinrin kan torukọ ẹ n jẹ Akinwande Oluwabusayọ, o si ji ẹrọ jẹnẹretọ ẹgbẹrun marundinlaaadọrun-un naira(85,000).

O ni bo ti kuro nibẹ lo tun ta kọṣọ si ṣọọbu keji ti i ṣe ti obinrin kan torukọ tiẹ n jẹ Fọlaṣade Mẹṣioye. Agbefọba sọ pe kọkọrọ ṣọọbu naa ni olujẹjọ fi ṣilẹkun wọle, ibi to si ti ri i ko ye ẹnikan.

Gaasi idana oni kilo marun-un (5kg cylinder) lo ji nibẹ pẹlu ṣia onike dọsinni kan. Ẹgbẹrun mẹjọ aabọ naira(8,500) lowo gaasi idana ọhun gẹgẹ bi agbefọba Lawrence ṣe wi, ẹgbẹrun lọna ọgbọn si ni wọn ta ṣia dọsinni kan to ko lọ ni ṣọọbu yii.

Apapọ gbogbo owo awọn nnkan wọnyi jẹ ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan le mẹtalelogun ataabọ (123,500).

Ẹsun mẹrin ni wọn fi kan olujẹjọ, iwa ọdaran si ni gbogbo ẹ labẹ ofin ipinlẹ Ogun ti wọn ṣe lọdun 2006, ijiya ẹwọn si wa fun un labẹ ofin.

Nigba to n dahun ibeere kootu pe ṣe o jẹbi awọn ẹsun naa, Adekunle ni loootọ loun jale, oun jẹbi ẹsun ti ile-ẹjọ fi kan oun.

Eyi ni Adajọ Dẹhinde Dipẹolu ṣe ni ko lọọ ṣẹwọn oṣu mẹfa-mẹfa fun ẹsun kọọkan to jẹbi ẹ.

O ni bo tilẹ jẹ pe aṣepọ ni yoo ṣẹwọn ọhun, ti ko si ni i lo ju oṣu mẹfa lọ, ṣibẹ, o gbọdọ jẹ pẹlu iṣẹ aṣekara. Bẹẹ ni ko si aaye owo itanran fun un rara.

Leave a Reply