Adelabu ki Makinde ku oriire, o jẹjẹẹ atilẹyin fun un

Ọlawale Ajao, Ibadan

Oludije funpo gomina lorukọ ẹgbẹ oṣelu Accord Party, Oloye Adebayọ Adelabu, ti ki Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde kuu oriire fun bo ṣe jawe olubori ninu idibo gomina to waye lọjọ Àbámẹ́ta, Sátidé, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii.

Ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan, Adelabu ṣapejuwe wiwọle ti Makinde wọle fun saa keji nipo gomina gẹgẹ bii ipe lati tubọ sin awọn ara ipinlẹ naa siwaju.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Bo tilẹ jẹ pe ipinlẹ Ọyọ ko ti i de ipo to yẹ ko wa, oore-ọfẹ mi-in lo ti wa fun Gomina Makinde bayii lati mu idagbasoke ba ipinlẹ Ọyọ.

Nigba to n tọka si awọn ẹka to nilo amojuto ninu iṣejọba ipinlẹ Ọyọ, Oloye Adelabu gba GSM, gẹgẹ bíi orukọ ti wọn tun n pe gomina yii, nimọran lati tubọ mojuto ọrọ eto aabo dáadáa.

Bakan naa lo tọka si ẹka eto ẹkọ gẹgẹ bii ohun to yẹ ki gomina yii ṣàtúnṣe gidi sí, paapaa ìpèsè ohun eelo ẹkọ fawọn akẹkọọ atawọn olukọ.

O waa ṣeleri atilẹyin rẹ fun iṣejọba tutntun náà, pàápàá, láti máa gba gomina naa nímọ̀ràn lati jẹ ki ijọba rẹ ṣaṣeyọri.

Leave a Reply