Adeleke ba ṣekupa ale iyawo ẹ l’Ayetoro, nile-ẹjọ ba ni ki wọn lọọ yẹgi fun un

Gbenga Amos, Abẹokuta

Bo tilẹ jẹ pe iyawo mẹta ni ọdaran ti wọn n porukọ ẹ ni Adeleke Bara yii ni, sibẹ, wọn lọkunrin naa jẹbi ṣiṣeku pa Oloogbe Ọlalẹyẹ Ọkẹ, tori o fura pe ọkunrin naa n yan ọkan ninu awọn iyawo oun l’ale, ṣugbọn ile-ẹjọ ti ni koun naa lọọ fiku ṣefa jẹ.
Adajọ Patricia Oduniyi, ti ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ogun, to wa niluu Ayetoro, nipinlẹ ọhun, lo gbe idajọ yii kalẹ lọjọ Aje, Mọnde, ogunjọ, oṣu Kẹfa yii.
Agbẹjọro ijọba, T. O. Adeyẹmi, ṣalaye ni kootu pe ọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un, ọdun 2018, ni Adeleke huwa apaayan ọhun, ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ, ni adugbo tawọn agbẹ n gbe ni Afodan, niluu Ijoun.
O ni niṣe ni ọdaran naa lọọ fibinu ka oloogbe ọhun mọ inu oko ẹ, lo ba fẹsun kan an pe o n laṣepọ pẹlu iyawo oun, ṣugbọn bi iyẹn ṣe fẹẹ bẹrẹ alaye pe ọrọ ko ri bẹẹ, Adeleke ti fa ibọn ṣakabula to gbe dani yọ, o si yinbọn naa lu Ọlalẹyẹ lori, lo ba pa a patapata.
Iṣẹlẹ yii lo sọ afurasi naa dero ahamọ ọlọpaa nigba ti wọn mu un, bo tilẹ jẹ pe o kọkọ sa lọ lẹyin iṣẹlẹ ọhun. Sugbon igbẹjọ bẹrẹ lẹyin tawọn ọlọpaa ti pari iwadii wọn.
Wọn ni iwa buruku gbaa ni ọdaran yii hu, ko si ba iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ Ogun mu.
Adajọ-binrin Oduniyi ni gbogbo ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ oun ti fihan pe loootọ ni iṣẹlẹ naa waye, ati pe olujẹjọ naa jẹbi iṣikapaayan. O ni niṣe lo ṣe idajọ oju-ẹsẹ fun oloogbe naa, ko si bọwọ fun ẹtọ ati iwalaaye ẹni ẹlẹni.
Tori naa, adajọ ni ki wọn sọ okun si Adeleke lọrun, ki wọn si jẹ ko rọ dirodiro titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ, tori igba teeyan ba fi winka ni yoo fi san an.

Leave a Reply