Adeleke fipa ba ọmọ ọdun mẹwaa lo pọ n’Idoani, o loogun owo loun fẹẹ fi i ṣe

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Adeniyi Adeleke, ti wa nikaawọ awọn ọlọpaa latari ẹsun ti wọn fi kan an pe o fipa ba ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹwaa lo pọ niluu Idoani, nijọba ibilẹ Ọsẹ.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ile kan naa ni Adeleke atawọn obi ọmọbinrin to fipa ba lo pọ naa gbe ni Idoani.
Ọmọkunrin naa ni wọn lo tan ọmọ alabaagbelepọ rẹ wọ yara rẹ, nibi to ti ba a sun tipatipa lọsan-an ọjọ kan ninu oṣu Kẹta, ọdun ta a wa yii, lẹyin to ṣakiyesi pe awọn obi rẹ ko si nile.
Ni kete ti iya ọmọbinrin ta a forukọ bo laṣiiri ọhun pada de lati ibi to lọ lọmọ rẹ ti kẹjọ to si ro fun un lori ohun toju rẹ ri labẹ buọda oni kinni ko mọ ọmọde tawọn obi rẹ n ba gbele.
Iya ọmọbìnrin naa ko si fọrọ falẹ lẹyin ti ọmọ rẹ ti royin ohun to sẹlẹ fun un, ileewosan lo mori le, nibi tawọn dokita ti fidi rẹ mulẹ pe loootọ ni ẹnikan fipa ba a lo pọ.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmi Ọdunlami, ni bo tilẹ jẹ pe inu oṣu Kẹta, ọdun yii, ni ọrọ ifipabanilopọ ọhun ti waye, ọsan ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, ni Abilekọ Bọsẹde Alọ to jẹ iya rẹ ṣẹṣẹ lọọ fẹjọ sun lagọọ ọlọpaa.
O ni awọn ti fi pampẹ ofin gbe afurasi afipabanilopọ naa, bẹẹ lo si ti jẹwọ pe oogun owo toun fẹẹ ṣe lo sun oun de idi iru iwa buburu ti oun hu.

Ọdunlami ni aṣọ pupa ati oruka oogun ti awọn ba ninu yara Adeleke lasiko ti awọn lọọ yẹ ibẹ wo si wa ni ikawọ awọn gẹgẹ bii ẹri.

Leave a Reply