Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Senetọ Ademọla Adeleke, ti kede Oloye Oyebọde Aderonkẹ Mary gẹgẹ bii iyalọja tuntun ti yoo rọpo Alhaja Awawu Asindẹmade to wa lori oye naa.
Ṣugbọn Alhaja Asindẹmade ti ni awada lasan ni ikede naa, nitori ko si ijọba to ni aṣẹ tabi agbara lati yọ iyalọja kankan lai ti i sọ ti Iyalọja-Jẹnẹra.
Ninu atẹjade ti Agbẹnusọ fun gomina, Mallam Ọlawale Rasheed, fi sita laipẹ yii lo ti sọ pe gomina ti kiyesi gbogbo ipa takuntakun ti Oloye Oyebọde n ko laarin awọn obinrin, idi niyẹn tijọba ṣe fi jẹ iyalọja.
Atẹjade naa ṣapejuwe Iyalọja tuntun gẹgẹ bii obinrin to ti mu idagbasole ba eto ọrọ-aje ati okoowo nipinlẹ Ọṣun, bẹẹ nijọba gbagbọ pe iyansipo rẹ yoo tun mu ipinlẹ Ọṣun goke agba sii.
Gomina Adeleke waa ṣeleri pe ọsẹ to n bọ ni ayẹyẹ ibura yoo waye fun Oloye Oyebọde lati le bẹrẹ iṣẹ iṣakoso rẹ ni kiakia.
Amọ ṣa, Iyalọja-Jẹnẹra to wa nibẹ, Alhaja Asindẹmade, ṣalaye pe ẹgbẹ ti ko rọgbọku le ijọba (NGO) ni ẹgbẹ awọn iyalọja, nitori naa, ko si ijọba to le tọwọ bọ iṣakoso rẹ.
O ni, ‘Emi ni Iyalọja-Jẹnẹra nipinlẹ Ọṣun, ko si ijọba to le yọ mi, koda saa wa ko ni asiko. NGO ni wa, emi ni mo si da a silẹ nipinlẹ Ọṣun, iyalọja ti ẹgbẹ PDP ni wọn yan yẹn, bi wọn ṣe ṣe nigba ti wọn dori aleefa lọdun 2003 ti ẹgbẹ wọn gbajọba niyẹn’.