Ademọla ati Hammed dero ẹwọn, ibọn ni wọn ba lọwọ wọn l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

 Latoko iroko lọ s’oko irokoto ni irinajo awọn genge meji yii, Lukman Hammed, ẹni ogun ọdun ati Ademọla Adio, ẹni ọdun mọkanlelogun, ile-ẹjọ ti paṣẹ pe ki wọn gba ahamọ ọlọpaa kọja si ọgba ẹwọn Kirikiri, latari bi ẹsun ti wọn fi kan wọn pe ibọn tawọn mejeeji o le ṣalaye bo ṣe jẹ, ni wọn ka mọ wọn lọwọ.

Ile-ẹjọ Majisreeti kan to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko, lawọn afurasi ọdaran mejeeji naa ti fara han niwaju adajọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Agbefọba to duro fun olupẹjọ, DSP Kẹhinde Ajayi, salaye nipa ẹsun to gbe awọn olujẹjọ naa de kootu, o ni ọjọ kẹwaa, oṣu kẹta, ọdun yii, ni awo ya mọ awọn mejeeji lori laduugbo Akala Base, Idi-Oro, ni Muṣhin, ipinlẹ Eko, nigba tawọn agbofinro fura pe wọn n bo nnkan kan mọ abẹ aṣọ, bi wọn si ṣe yẹ nnkan naa wo, ibọn pompo agbelẹrọ kan ni wọn ba lọwọ ọkan, ọta ibọn rẹpẹtẹ ti wọn o ti i yin lẹni keji n daṣọ bo lori ni tiẹ, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe wọn.

Lahaamọ ọlọpaa ti wọn fi wọn si, Ajayi sọ pe awọn mejeeji ko ri alaye gunmọ kan ṣe lori iṣẹlẹ naa, wọn o si ti i jẹwọ ibi ti wọn ti pade ohun ija oloro ti wọn n ko kiri, ṣugbọn wọn ni wọn jẹwọ pe iṣẹẹbi kan lawọn fẹẹ lọọ ṣe ti wọn fi mu awọn.

Ẹsun nini nnkan ija oloro nikaawọ lai gba aṣẹ, igbimọ pọ lati huwa ọdaran ati igbiyanju lati da omi alaafia ilu ru ni wọn fi kan wọn, leyi ti wọn lo tako isọri kọkanlelaaadọta, (51) isọri okoolelọọọdunrun ati mẹwaa abala kẹta (330c) ati isọri okoolenirinwo din mẹsan-an (411) ninu iwe ofin iwa ọdaran tọdun 2015 ti ipinlẹ Eko.

Nigba ti wọn bi wọn leere boya wọn jẹbi, awọn afurasi naa lawọn o jẹbi, l’Adajọ A. O. Ajibade ba paṣẹ pe ki wọn taari wọn sọgba ẹwọn Kirikiri, ibẹ ni ki wọn wa titi di ọjọ kẹrin, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ti igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju lori ọrọ naa.

Leave a Reply