Adeshina di Aarẹ banki idagbasoke Afrika lẹẹkeji

Oluyinka Soyemi

Ọmọ ilẹ wa, Akinwumi Adeshina, ti wọle lẹẹkeji gẹgẹ bii Aarẹ banki idagbasoke ilẹ Afrika fun ọdun marun-un mi-in.

Eyi waye lonii lẹyin ipade ti awọn alaṣẹ banki naa ṣe lori ayelujara, bẹẹ ni ko sẹni to ba a du ipo naa.

Laipẹ yii ni wọn fi ẹsun ipaṣipayọ owo kan Adeshina, ṣugbọn wọn pada da ẹjọ naa nu nitori ko lẹsẹ nilẹ, eyi to fun un lanfaani lati du ipo yii nigba keji.

Tẹ o ba gbagbe, ọdun 2015 ni Adeshina di aarẹ banki yii, eyi to sọ ọ di ọmọ Naijiria akọkọ to di ipo naa mu.

Ẹni ọgọta ọdun ni ọkunrin naa, o si ti ṣe minisita fun nnkan ọgbin ati idagbasoke igberiko nilẹ Naijiria laye iṣejọba Ọmọwe Goodluck Jonathan.

Leave a Reply