Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
O tojọ mẹta ti ọkunrin kan, Adetoro David, ti n jẹjọ jiji ọmọ ọlọmọ gbe lagbegbe Oju-Oore, l’Ọta. Adajọ ti ju u sẹwọn ọdun marun-un bayii, wọn ni gbogbo ẹri lo foju han pe o jẹbi ẹsun naa.
Adajọ O. I Oke lo sọ David, ẹni ọdun marundinlaaadọta (45) sẹwọn. Kootu Majisreeti Ọta ti wọn ti n gbọ ẹjọ naa latilẹ wa ni wọn ti dajọ wayi.
Agbefọba Grace Adebayọ ṣalaye pe David Adetoro ati obinrin kan to ti sa lọ bayii ni wọn jọ ji ọmọkunrin ọmọ ọdun meji naa gbe.
O ni iya ọmọ naa ran ẹgbọn ọmọ yii niṣẹ, iyẹn si mu aburo ẹ to jẹ ọmọ ọdun meji dani. Afi bi David atobinrin naa ṣe pe wọn pe ki wọn wa, wọn fun ẹgbọn lowo pe ko lọọ ra bisikiiti wa fun aburo ẹ, wọn si ni ko sare lọ, awọn yoo maa ba a ṣọ aburo ẹ titi ti yoo fi de.
Igba ti ẹgbọn de, ko ba awọn eeyan naa mọ debi ti yoo ri aburo ẹ, bo ṣe di pe wọn n wa a latigba naa niyẹn.
David nikan lawọn ọlọpaa pada ri mu lẹyin iwadii, wọn si fẹsun ijinigbe ati igbimọ ṣiṣẹ ibi kan an. Bo tilẹ jẹ pe o loun ko jẹbi latigba tigbẹjọ ti n waye, sibẹ, gbogbo ẹri ni kootu sọ pe o foju han pe oun lo ji ọmọ naa gbe.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Adajọ Oke ni ki David Adetoro lọọ ṣẹwọn ọdun marun-un pẹlu iṣẹ aṣekara. Ko faaye owo itanran silẹ fun un rara, ẹwọn taara lo ni ki wọn maa gbe e lọ.