Adetoro yii yoo ṣẹwọn o, ọmọ ọdun meji lo ji gbe l’Oju-Oore

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan-an to ṣẹṣẹ pari yii, ọmọdekunrin kan to jẹ ọmọ ọdun meji pere, Marvelous Oluwọle, di awati laduugbo Oju-Oore, l’Ọta, nipinlẹ Ogun. Baale ile kan, Adetoro David, ati obinrin kan ni wọn ni sọ pe wọn ji ọmọ naa gbe, ohun to gbe David de kootu Majisreeti Ọta lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keji, oṣu kẹwaa, yii ree.

Ẹsun jiji ọmọ gbe ati igbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi ni wọn fi kan Adetoro, ẹni ti Agbefọba,  E.O Adaraloye, sọ nipa ẹ pe ni nnkan bii aago mẹrin aabọ irọlẹ ọjọ naa loun atobinrin to ti sa lọ naa jọ duro lagbegbe Oju-Oore. O ni asiko naa ni wọn ri Marvelous ati ẹgbọn ẹ to n jẹ Kẹhinde, ti wọn lọ si ibi ti iya wọn ran wọn.

Agbefọba ṣalaye pe olujẹjọ yii ati obinrin ti wọn jọ duro, ṣẹwọ si ẹgbọn Marvelous pe koun ati aburo ẹ wa. O ni nigba tawọn ọmọ naa de ọdọ wọn, niṣe ni wọn fun Kẹhinde to jẹ agba ninu wọn lowo pe ko lọọ ra bisikiiti wa. Kọmọ naa too ti ibi to ti lọọ ra bisikiiti ọhun de ni Adetoro ati obinrin naa ti gbe Marvelous lọ, lọmọ ba di awati.

Teṣan ọlọpaa Onipaanu ni Iya Marvelous mu ẹjọ lọ, lẹyin ifisun naa si lọwọ ba David Adetoro, ẹni keji rẹ ni wọn ko ti i ri mu.

Olujẹjọ loun ko jẹbi ẹsun naa pẹlu alaye, iyẹn ni Adajọ A.O Adeyẹmi ṣe faaye beeli silẹ fun un pẹlu ẹgbẹrun lọna igba naira ati oniduuro meji niye kan naa.

O paṣẹ pe awọn oniduuro naa gbọdọ maa gbe nitosi kootu, wọn gbọdọ niṣẹ gidi lọwọ, wọn si gbọdọ le ṣafihan iwe-ẹri owo ori sisan wọn.

Igbẹjọ di ọjọ kẹjọ, oṣu yii.

Leave a Reply