Adeyẹmi ti jẹwọ o: Mo ji ewurẹ ti mo fi ṣekomọ ọmọ mi n’Ipokia

Gbenga Amos
Ahamọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Idiroko lọkunrin ti wọn n pe ni James Adeyẹmi wa bayii latari bo ṣe jẹwọ pe loootọ loun ji ewurẹ elewurẹ kan, toun si pa a, lati ṣayẹyẹ ikomọjade ọmọ toun ṣẹṣẹ bi, tori ko sowo lọwọ oun lati dana ounjẹ loun ṣe da ọgbọnkọgbọn bẹẹ.
Alukoro ẹṣọ alaabo So Safe nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Moruf Yusuf, lo sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Furaidee, ọsẹ yii.
Wọn ni Agboole Gbenga, niluu Ihunbọ, nijọba ibilẹ Ipokia, nipinlẹ Ogun, lafurasi ọdaran yii n gbe, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, si lọwọ awọn So Safe ba a, ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ, nibi to ti n dumbu ẹran ẹlẹran to ji gbe.
Awọn aladuugbo kan ti wọn kẹẹfin James bo ṣe n lọ to n bọ, ninu igbo ṣuuru kan ti ko fi bẹẹ jinna silẹ ẹ lọjọ naa, ni wọn fura si i, ti wọn si ta awọn ẹṣọ So Safe lolobo, nigba t’Ọlọrun yoo si mu un, nibi to ti n dumbu ẹran naa lọwọ, to fẹẹ bẹrẹ si i kun un ni wọn ka a mọ, lo ba jẹwọ pe oun kọ loun ni in, oun o mọ ẹni to ni in, oun ji i ni.
Ni ọfiisi So Safe ti wọn mu un lọ pẹlu ẹsibiiti ẹ, afurasi ọdaran naa jẹwọ pe ole gidi loun, ẹẹmẹta loun ti lọọ fọ ṣọọbu kan to wa ni Kilomita kin-in-ni, ọna Ita-Egbe, Ihunbọ, toun si ji ọja wọn ko. Lara ọja to loun ji ni katọọnu ada mẹta, eyi ti aadọrun-un wa ninu rẹ, ẹrọ ti wọn fi n finko kan, kẹmika pakopako oriṣiiriṣii mẹrindinlọgbọn, baagi fatalaisa NPK marun-un, igo Guard Force meje, kẹmika Morshal meji, ati apo agbado diẹ.
Wọn ni ko mu awọn de ibi to tọju awọn ẹru ẹlẹru ọhun pamọ si, bo tilẹ jẹ pe o ti ta diẹ ninu wọn, sibẹ, wọn ri ọpọ lara awọn ẹru ole naa, titi kan ọkada Bajaj alawọ pupa kan ati buutu oko meji, wọn si ko wọn.
Ni bayii, wọn ti fa James le awọn ọlọpaa lọwọ, pẹlu awọn ẹsibiiti ti wọn ba lọwọ ẹ, fun iṣẹ to lọọrin lori ọrọ yii.

Leave a Reply