Adiẹ jẹfun ara wọn: Ẹgbọn ta aburo rẹ lowo pooku fawọn to n feeyan ṣowo ẹru, lo ba lọọ fowo ṣegbeyawo

Adeoye Adewale

Titi di asiko ta a n koroyin yii jọ lọwọ lọrọ obinrin kan, Omidan Blessing Okonkwo, ẹni ọdun mẹrinlelogun, to ta aburo rẹ ni gbanjo fawọn to n feeyan ṣowo ẹru laarin ilu ṣi n ya lẹnu gidi. Ẹgbẹrun lọna irinwo o le ẹgbẹrun mẹwaa Naira (410,000) lowo ti afurasi ọdaran ọhun ta aburo rẹ tọjọ ori rẹ ko ju ọdun mẹta pere lọ.

ALAROYE gbọ pe agbegbe Mubi, nipinlẹ Adamawa, ni afurasi ọdaran ọhun n gbe, nigba ti asiko igbeyawo rẹ ti sun mọle ti ko sowo lọwọ rẹ lo ba ro o lọkan ara ẹ pe koun ta aburo oun fawọn araalu kan ti wọn n feeyan ṣowo ẹru nilẹ Ibo lọhun-un.

O si da a bii ọgbọn, o sọ fun iya rẹ, Abilekọ Hauwa Lawan, to n gbe lagbegbe Rimirgo, nijọba ibilẹ Askira, nipinlẹ Borno, pe oun fẹẹ ran ọmọ naa lọ sileewe alakọọbẹrẹ kan ti ko fi bẹẹ jinna pupọ sibi to n gbe. Nigba to to ọjọ mẹta kan ti iya ọmọ naa ko gburoo ọmọ rẹ lo ba kan an nipa fun Blessing pe ko jẹ k’oun ba aburo rẹ sọrọ lori foonu. Lọrọ ba pesi jẹ, Blessing ko le pese ọmọ naa fun iya wọn lati le ri i ba sọrọ, laṣiiri ba tu sita.

Awọn agbefọba ipinlẹ naa fọwọ ofin gba a mu, ọdọ wọn lo ti jẹwọ pe, Abilekọ Efunaya Nabufr to n ṣiṣẹ okoowo ẹru niluu Enugu loun ta ọmọ naa fun.

Blessing ni ‘Kẹ ẹ si maa wo o, ilu to le koko lo jẹ ki n ṣiwa-hu lawujọ, ẹgbẹrun lọna irinwo o le ẹgbẹrun mẹwaa Naira lowo ti mo ta ọmọ naa fun oniṣowo okoowo ẹru kan to n gbe niluu Enugu. Mo lo diẹ lara owo naa lati fi ra ẹrọ ti wọn fi n lọ ata, mo fẹẹ bẹrẹ iṣẹ gidi lẹyin ti mo ba ṣegbeyawo alarinrin ti mo n palẹmọ rẹ lọwọ bayii. Mo si ko ẹgbẹrun lọna igba Naira fun ọkọ afẹsọna mi pe ko lo owo naa lati fi ra awọn nnkan kọọkan ta a nilo fun eto igbeyawo wa to n bọ lọna’.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa, S.P Suleiman Nguroje, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, ọdun yii, sọ pe Abilekọ Hauwa Lawan, ti i ṣe Iya Blessing ati ọmọ ti wọn ta ni gbanjo lo lọọ fọrọ ohun to awọn ọlọpaa agbegbe Rimirgo, nijọba ibilẹ Askira-Uba nipinlẹ Adamawa letim tawọn yẹn si tete fọwọ ofin mu un nile rẹ. Afurasi ọdaran ọhun ti jẹwọ pe loootọ loun ta ọmọ naa lowo pọọku fawọn kan nilẹ Ibo.

Ọga ọlọpaa patapata nipinlẹ naa, C.P Dankombo Morris, ti paṣẹ fawọn ọlọpaa agbegbe naa pe ki wọn wa ọmọ ọhun jade nibi ti wọn ta a si. Wọn si ti mu Blessing Friday, ẹni ọdun mẹrinlelogun, ati Efunaya Nabur, ẹni ọdun marundinlogoji, ti wọn lọwọ ninu iwa ti ko bofin mu naa.

Alukoro ni awọn maa too foju gbogbo wọn bale-ẹjọ.

Leave a Reply