Adigunjale atawọn Amọtẹkun doju ibọn kọra wọn l’Ọyọọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Bii igba ti wọn wa loju ogun lọrọ ri laarin ikọ eleto aabo ilẹ Yoruba, Amọtẹkun, ẹka ipinlẹ Ọyọ, atawọn ogboju adigunjale kan nigba ti awọn mejeeji fija pẹẹta, ti wọn si n rọ̀jò ibọn ranṣẹ sira wọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ana.

Ni nnkan bii aago meji aabọ ọsan niṣẹlẹ ọhun waye laduugbo Baara, niluu Ọyọ. Nigbẹyin ija naa, ibọn ba oṣiṣẹ Amọtẹkun kan to n jẹ Amo Ṣangodoyin nikun, meji ninu awọn afurasi adigunjale naa, Tiamiyu Abiọdun ati Saka Rokeeb si fara gbọta.

Oludari ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ, Ọgagun-fẹyinti Ọlayinka Ọlayanjusọ, sọ pe lasiko ti awọn ọbayejẹ eeyan naa n fibọn ja awọn araadugbo Baara, niluu Ọyọ, lole lawọn araadugbo ọhun fi iṣẹlẹ naa to awọn leti lori ẹrọ ibanisọrọ, ti awọn eeyan oun si ta lọọ koju awọn igaara ọlọṣa naa.

Amọ ṣa, ohun ti awọn Amọtẹkun ro kọ ni wọn ba pade nitori kaka ki awọn ẹruuku wọnyi sa lọ nigba ti awọn Amọtẹkun ba wọn lalejo, ibọn ni wọn fi ki wọn kaabọ, ibọn si ba ọkan ninu awọn ọmoogun agbofinro naa nikun.

Lọgan lawọn eleto aabo naa mura ija, ti awọn ikọ mejeeji si bẹrẹ si i jọ dana ibọn funra wọn ya karakara.

Ọwọ ibọn ba bii meji ninu awọn kọlọransi wọnyi, wọn si woye pe ija yii ki i ṣe ohun ti awọn le bori, nigba naa ni wọn pẹyin da, n ni wọn ba fere ge e.

Ṣugbọn ẹ̀pa kò bóró fun ikọ awọn adigunjale ẹlẹni mẹrin yii, nitori gbogbo wọn pata lọwọ awọn Amọtẹkun tẹ tibọn-tibọn ọwọ kaluku wọn.

Orukọ awọn afurasi ọdaran naa ni Idowu Taofeek, Yekin Awwal, Tiamiyu Biọdun ati Saka Rokeeb.

Ajagunfẹyinti Ọlayanju fidi ẹ mulẹ pe nibi ti awọn agbofinro ti n sinmi aṣeyọri yii lọwọ ni ipe tun ti wọle sori aago awọn Amọtẹkun, wọn lawọn adigunjale mi-in tun n pitu lọwọ nibomin-in nigboro ilu Ọyọ kan naa.

Ninu iṣẹlẹ keji yii lọwọ ti ba ọkan ninu awọn adigunjale naa ti wọn pe lakẹkọọ fasiti kan nipinlẹ Ọyọ.

 

Gẹgẹ bi ọga awọn Amọtẹkun ṣe fidi ẹ mulẹ, awọn eleto aabo yii ni wọn gbe Biọdun, ẹni ogun ọdun (20) ati Rokeeb ti i ṣe ẹni ọdun mejidinlogun (18) lọ sileewosan ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa niluu Ọyọ fun itọju nigba ti wọn fa awọn mẹta yooku le awọn ọlọpaa lọwọ ni teṣan wọn to wa ni Durbar, niluu Ọyọ.

Leave a Reply