Adigunjale mẹtadinlogun ha sọwọ ọlọpaa l’Ekoo, ibọn mẹta ati ọpọlọpọ oogun ni wọn gba lọwọ wọn

Faith Adebọla, Eko

Mẹtadinlogun lara awọn afurasi adigunjale to n daamu awọn olugbe agbegbe Lẹkki si Ajah, ni Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lọwọ awọn ti ba, wọn si ti fi wọn sahaamọ.

Orukọ diẹ lara wọn ni Abdulrasheed Adebayọ, ẹni ogun ọdun, Ọladapọ Job, ẹni ọdun mejilelogun, Abdulraheem Sidibaba, ẹni ogun ọdun, Tajudeen Abdullahi, Agbaje Sunday, ẹni ọdun mọkanlelogun, atawọn mejila mi-in.

Ba a ṣe gbọ, o ti pẹ tawọn ọtẹlẹmuyẹ ti n finmu finlẹ nipa awọn firi-nidii-ọkẹ, alọ-kolohun-kigbe ẹda wọnyi, ti wọn si ti sami sawọn ibuba wọn gbogbo lagbegbe naa, ki wọn too lọ ya bo wọn ni nnkan bii aago meji aabọ oru ọjọ kẹrinla, oṣu yii, nigba tọwọ ti pa, tẹsẹ ti pa.

Wọn ni bi wọn ṣe n mu wọn ni wọn n gbọn yara wọn yẹbẹyẹbẹ, wọn ba ibọn agbelẹrọ mẹta lọwọ wọn, katiriiji ọta ibọn ti wọn o ti i yin mẹrin, ada, ọbẹ, bileedi atawọn nnkan ija mi-in, oogun abẹnu gọngọ ko si gbẹyin lapo wọn.

Adejọbi to jẹ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ni iwadii ti wọn kọkọ ṣe fihan pe awọn afurasi wọnyi ni wọn maa n ja awọn to n ṣowo POS lagbegbe naa lole, wọn lawọn kan lara wọn jẹwọ pe awọn maa n ṣe bii kọsitọma to fẹẹ gbowo tabi sanwo, wọn aa si fibọn gba owo tawọn ẹni ẹlẹni ti pa lọwọ wọn, tabi ki wọn fipa mu wọn lati fowo ranṣẹ sakanti banki wọn.

Adejọbi ni awọn afurasi tọwọ ba yii ti n darukọ awọn mi-in tawọn ọlọpaa ṣi n wa bayii lara wọn.

Ṣa, iwadii ṣi n lọwọ lori awọn mẹtadinlogun yii lẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Panti, ni Yaba. Wọn ni wọn o ni i pẹ balẹ sile-ẹjọ tiṣẹ iwadii ba ti pari.

Leave a Reply