Adigunjale ni Saidi, ibọn ibilẹ lo fi n da wọn laamu ni Festac

Faith Adebọla, Eko

 

 

Saidi Adewale lorukọ ọmọ ọdun mẹtadinlogoji yii, ọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, lo wa bayii, ibẹ ni wọn ti n ṣe e lalejo latari ibọn ibilẹ ti wọn ba lọwọ ẹ, wọn nibọn ọhun lo fi n daamu awọn eeyan lagbegbe Festac, nijọba ibilẹ Amuwo-Ọdọfin, l’Ekoo.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, Olumuyiwa Adejọbi, sọ f’ALAROYE lori ikanni wasaapu rẹ pe ọga ọlọpaa tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan si tesan Festac, CSP Fẹmi Iwasokun, lo ko awọn ẹmẹwa ẹ sodi lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, wọn bẹrẹ si i wa awọn ibuba tawọn janduku ati adigunjale n sa pamọ si lagbegbe ọhun kiri, ki wọn le palẹ wọn mọ.

Eyi ni wọn n ṣe lọwọ ti wọn fi ri awọn gende mẹta kan lori ọkada ni randabaotu Aboju, lọna marosẹ Badagry, ni wọn ba gba fi ya wọn. Wọn ni bawọn afurasi ọdaran naa ṣe kiyesi i pe awọn ni mọto ọlọpaa to n tẹle wọn yii n le bọ, niṣe ni wọn ṣẹ kọna sinu igbo, wọn bẹ danu lori ọkada, wọn sa lọ.

Ṣugbọn ọwọ tẹ ọkan ninu wọn, Saidi Adewale, awọn ọlọpaa si gbe oun ati ọkada ti wọn gun, o di teṣan wọn.

Agọ ọlọpaa ni Saidi ti jẹwọ pe oun ko ni ibi pato kan toun n gbe, ibi ti ilẹ ba ṣu oun si loun n sun ni toun, nigba to tiẹ jẹ pe oru niṣẹ tawọn n ṣe maa n bọ si. Nigba ti wọn si beere iṣẹ ti jagunlabi n ṣe, o ni gbewiri lawọn, ole lawọn n ja, irinṣẹ toun si ni ibọn ti wọn ba lapo oun yii.

Ibi to sọrọ de niyi ti wọn fi lọọ fa a kalẹ fawọn agbofinro ni Panti.

Adejọbi ni iṣẹ iwadii ṣi n lọ lọwọ lori keesi ẹ, ati pe afurasi naa ti n ran awọn agbofinro lọwọ lati le tete ri awọn to sa lọ, atawọn to ku ninu ikọ adigunjale wọn mu, ki gbogbo wọn le lọọ kọgbọn ni kootu laipẹ.

Leave a Reply