Adigunjale ya wọ ile awọn akẹkọọ Poli Ilaro, wọn ba awọn akẹkọọ-binrin wọn lo pọ

Monisọla Saka
Koju ma ribi, gbogbo ara loogun ẹ lawọn akẹkọọ Poli Ilaro fi ọrọ naa ṣe pẹlu bi wọn ṣe sa asala fun ẹmi wọn lọwọ awọn adigunjale to n figba gbogbo ṣọṣẹ laduugbo wọn.
Awọn adigunjale kan ni iroyin fidi ẹ mulẹ pe wọn ya bo ilegbee awọn akẹkọọ ileewe giga Poli ijọba apapọ to wa ni Ilaro, wọn fipa ba awọn akẹkọọ-binrin lo pọ, wọn si tun ko awọn nnkan ini wọn bii foonu, kọmputa agbeletan ti wọn n pe ni ‘laptop’, owo ati awọn nnkan miiran lọ.
Akọroyin PUNCH ni awọn adigunjale ọhun ti wọn to bii mẹjọ ni wọn ka awọn akẹkọọ to n gbe ni awọn ile to wa ni ita ileewe ni awọn adugbo bii School 2 ati Deuteronomy mọle.
Ẹni kan ti ko darukọ ara rẹ ni “Alẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ni awọn agbebọn kan ti a ko mọ tun deede ya de. Wọn bẹ wọnu ile, wọn n yinbọn leralera, wọn si n fi tipa jalẹkun wọle. Koda, ọta ibọn ba akẹkọọ kan lẹyinju.
“Wọn fi tipa ba awọn akẹkọọ-binrin lo pọ, wọn si tun ko awọn nnkan ini wọn lọ. A n bẹbẹ fun iranlọwọ, nitori o ti to ọsẹ kan ta a ti wa lẹnu ọrọ yii. A o si rẹni ba wa ṣe nnkan kan si i, pupọ awọn obinrin wa ni wọn ti fipa ba lo, ọpọlọpọ ile ni wọn si ti ba jẹ. A o mọ’hun to n ṣẹlẹ, ẹyin ọmọ Naijiria, ẹ gba wa o”.
Akẹkọọ mi-in to tun sọrọ nipa iṣẹlẹ yii ni ogunlọgọ awọn akẹkọọ lo ti sa kuro lagbegbe ileewe lọ si ile obi kaluku wọn nigba ti ko si ojutuu si ọrọ ọhun”.
A gbọ pe awọn lanlọọdu agbegbe ti awọn akẹkọọ pọ ju si ni Ilaro ṣepade pọ ni ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, lati sọrọ lori eto aabo ilu. Iwadii fi han pe lẹyin ipade ọhun, awọn ẹgbẹ idagbasoke adugbo ni Ilaro fẹnu ko pe adugbo kọọkan gbọdọ ni ọdẹ alẹ to n ṣọ wọn, ki awọn akẹkọọ naa si gba fọọmu iyalegbe.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi, ni oun o mọ si iṣẹlẹ ọhun. O waa ṣeleri lati jabọ pada fun wọn ni kete toun to ba ti ba ọga ọlọpaa Ilaro sọrọ.
Amọ ṣa o, Oluranlọwọ pataki fun gomina ipinlẹ Ogun, Azeez Adeyẹmi, fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, ṣugbọn o ni ọrọ ifipabanilopọ ti wọn fi kun un loun ko le sọ.
O ni ijọba ipinlẹ Ogun n sapa wọn lati wa ọna abayọ si ọrọ naa, o fi kun un pe ẹgbẹ awọn akẹkọọ ilẹ Naijiria, iyẹn NANS, n ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba lati dawọ ikọlu si awọn akẹkọọ poli ọhun duro.
O fi lede pe awọn yoo ṣepade pẹlu Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle, lati wa ojutuu si iṣoro ọhun.

Leave a Reply