Stephen Ajagbe, Ilorin
Afurasi ẹni ọdun mẹtalelogoji kan, Ọlawale Adisa, ti dero ahaamọ ileeṣẹ ọlọpaa niluu Ilọrin bayii nitori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an.
Adisa ni wọn wọ lọ sile-ẹjọ Magisreeti kan ni Ilọrin fẹsun pe o gbimọ-pọ pẹlu awọn kan lati pa Suraju Popoọla, ọmọ bibi mọlẹbi Balogun, niluu Ọffa, nipinlẹ Kwara.
Akọsilẹ awọn ọlọpaa ṣalaye pe lẹyin ti wọn pa ọkunrin naa tan, wọn tun ri oku rẹ mọlẹ sibi ti ẹnikankan ko ti le ri i.
Ṣugbọn akara akara awọn afurasi naa tu sepo nigba ti ọwọ tẹ Adisa, to si bẹrẹ si i ka boroboro. Awọn ọlọpaa pada tọpinpin saare ti wọn ri oloogbe naa mọ, ti wọn si ba oku naa nibẹ.
Agbẹjọro ijọba, Yusuf Nasir, sọ fun ile-ẹjọ pe iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ẹjọ naa. O bẹ adajọ lati ma gba oniduuro Adisa nitori ẹsun ipaniyan ni wọn fi kan an, ṣugbọn ko wa lọgba ẹwọn titi tiwadii to n lọ yoo fi dopin.
Adajọ Muhammed Ibrahim paṣẹ pe ki afurasi naa wa lahaamọ ẹka to n gbogun ti iwa ọdaran, CID, nileeṣẹ ọlọpaa, o si sun ẹjọ naa siwaju titi di igba ti iwadii yoo fi pari lori ẹsun ti wọn fi kan an.