Ado oloro bu gbamu nitosi ileewe kan ni Kano, ọpọ ẹmi lo ṣofo

Jọkẹ Amọri
Ado oloro kan bu gbamu ni agbegbe ti wọn n pe ni Aba Road, to wa ni Sabongeri, niluu Kano, nipinlẹ Kano, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii. Ọpọlọpọ awọn eeyan lo ku, ninu eyi ti awọn ọmọleewe wa, bẹẹ ni awon mi-in fara pa yanna yanaa.
Ko sẹni to ti mọ ẹni to gbin ado oloro naa sibẹ, ṣugbọn ado oloro to gbina ọhun ṣakoba fun awọn ile to wa ni agbegbe ibi to ti ṣẹlẹ, leyii to ṣee ṣe ko jẹ pe ileewe kan wa nitosi ibẹ.
Ninu fidio kan to gba ori ẹrọ ayelujara kan nipa iṣẹlẹ yii, niṣe ni onikaluku n sa asala fun ẹmi rẹ, ti wọn si n gbe awọn ọmọ keekeeke ti wọn jẹ akẹkọọ digbadigba kuro nibi iṣẹlẹ naa.
Gẹgẹ bi Kọmiṣanna feto iroyin nipinlẹ naa, Mallam Muhamad Garba, ṣe sọ, o ni ki i ṣe ileewe ni ado oloro naa ti dun bi awọn kan ṣe n gbe e kiri, o ni ileetaja kan ti wọn n pe ni Animal Feeds Stores, to wa ladojukọ ileewe naa ni ado oloro yii ti dun.
O ni awọn ko ti i le sọ awọn ohun to bajẹ ati bi iṣẹlẹ naa ṣe ba nnkan jẹ to. O rọ awọn eeyan agbegbe naa pe ki wọn fọkan balẹ, nitori ijọba ti n ṣa gbogbo ipa lati wa ojutuu sọrọ naa.

Leave a Reply