Afẹnifẹre gboṣuba nla fawọn OPC ti wọn mu Wakili Isikilu to n da awọn eeyan laamu n’Ibarapa

Ẹgbẹ Afẹnifẹre ti fidimule wọn han si bi ọwọ ṣe tẹ ọga awọn Fulani, Isikilu Wakilu, to ti n da awọn eeyan Ibarapa laamu, bẹẹ ni wọn ti gboṣuba ‘o kare’ fun awọn ọmọ ẹgbẹ OPC labẹ akoso Iba Gani Adams, to mu ọkunrin naa atawọn abẹṣinkawọ ẹ.

 

Ninu ọrọ ti Akọwe agba fun ẹgbẹ Afẹnifẹre,Yinka Odumakin, fi sọwọ si ALAROYE lo ti sọ pe aṣẹyọri nla ni ẹgbẹ OPC ipinlẹ Ọyọ labẹ akoso Iba Gani Adams ṣe, ati pe ohun iwuri ni lati mu ẹni to n ko wahala ba awọn eeyan agbegbe naa.

 

O ni, “O pẹ ti Isikilu Wakilu atawọn eeyan ẹ ti n da awọn eeyan agbegbe ọhun laamu, ohun idunnu lo si jẹ pe ọwọ ti tẹ ẹ bayii pẹlu awọn ọmọ ẹ ti wọn jọ n ṣiṣẹ ibi lagbegbe naa. Ohun ibanujẹ lo jẹ pe pẹlu gbogbo wahala ti awọn eeyan Ibarapa n doju kọ, ileeṣẹ ọlọpaa atawọn ẹṣọ agbofinro mi-in ko ri ohunkohun ṣe lati fọwọ ofin mu ọkunrin yii. Ni bayii, a dupẹ tọwọ awọn OPC ti tẹ ẹ, bẹẹ niṣẹlẹ yii ti fidi ẹ mulẹ idi to fi yẹ ki a ni atunto to ye kooro lorilẹ-ede yii.”

 

Odumakin fi kun ọrọ ẹ pe ka ni ki i ṣe awọn agbaagba kan nipinlẹ Ọyọ ti wọn tete dide sọrọ ọhun ni, o lo ṣee ṣe ki awọn ọlọpaa di awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ti wọn ṣaṣeyọri yii lọwọ, ati pe dipo bi wọn ṣe mu Wakilu yii, awọn OPC lawọn ọlọpaa mas ti ọran mọ, ti wọn yoo si rọ wọn da si atimọle.

 

Bakan naa lo sọ pe aṣẹyọri yii tubọ fidi ẹ mulẹ pe awọn eeyan ti wọn wa lawọn igberiko paapaa naa ni ipa nla ti wọn le ko lori eto aabo ara wọn, ti ijọba ba faaye ẹ silẹ fun wọn.

Ọjọ Aiku, Sannde yii, lọwọ tẹ ọkunrin naa atawọn ọmọ ẹ. Ninu fidio ti awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ti wọn mu un fi sita ni baba agbalagba yii ti diju mọri, ti ko sọ ohunkohun si gbogbo awọn ibeere ti wọn n bi i.

Ọkan lara awọn ọmọ OPC ti wọn n beere ọrọ lọwọ wọn sọ pe bi awọn ṣe yọ si ibi ti wọn n gbe ni ọkan ninu wọn ti dana ibo bo awọn, ṣugbọn ti ohunkohun ko ṣẹlẹ si ẹnikẹni.

O lẹni to yinbọn ọ̀hun ti sa lọ, bẹẹ lọkan ninu awọn ẹni tọwọ tẹ pẹlu Wakilu sọ pe Jamil lẹni naa n jẹ.

Awọn OPC yii ti sọ pe awọn yoo fa wọn le ọlọpaa lọwọ, nibi ti igbesẹ to yẹ yoo ti waye.

 

Leave a Reply