Afẹnifẹre ko ni i ṣatilẹyin fẹnikẹni, afi ti wọn ba kọkọ tun iwe ofin Naijiria ṣe

Faith Adebọla, Eko

 Ẹgbẹ Afẹnifẹre, ẹgbẹ to n jijangbara fun ilẹ Yoruba ti sọ pe awọn ko ni i ṣatilẹyin fun ẹnikẹni lati de ipo aarẹ ati awọn ipo oṣelu mi-in ninu eto idibo gbogbogbo to n bọ lọdun 2023, lai jẹ pe ijọba kọkọ ṣatunṣe to yẹ si iwe ofin ilẹ wa, ti wọn si mu awọn aleebu pataki kan kuro ninu ofin ọhun.

Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre, Oloye Ayọ Adebanjọ, lo sọrọ yii fun iweeroyin Punch, nigba ti wọn bi i leere ero ẹgbẹ naa lori igbesẹ Aṣiwaju Bọla Tinubu to ṣabẹwo si Aarẹ Muhammadu Buhari lọjọ Aje, Mọnde, lati kede pe oun maa dupo aarẹ ninu eto idibo to n bọ.

Alagba Adebanjọ sọ pe: “Ohun to ṣe pataki lakooko yii si ẹgbẹ Afẹnifẹre ni atunṣe to yẹ ko kọkọ waye si ofin ilẹ wa, ilana oṣelu, ati awọn eto iṣakoso Naijiria.

“Afi ka kọkọ da orileede yii pada si eto ilana iṣakoso to wa deede, to si tọna, ki awọn ijọba ẹlẹkunjẹkun si lominira lati ṣakoso bo ṣe yẹ, ki i ṣe iru eyi ti a ti n ba bọ titi dasiko yii. Awọn nnkan to wọ ninu iwe ofin naa ṣe pataki ka kọkọ tun wọn ṣe, iwa omugọ ni lati sọ pe a o maa lo o lọ bẹẹ, ka si reti pe ki nnkan rere tibẹ yọ.

“Tinubu ni ẹtọ labẹ ofin lati sọ pe oun fẹẹ dupo aarẹ, gbogbo eeyan naa lo niru ẹtọ bẹẹ, ko si nnkan babara kan ninu iyẹn.

“Emi o sọrọ nipa Tinubu lasiko yii, mi o tiẹ le sọrọ nipa ẹnikẹni rara, ohun to jẹ wa logun ni pe ki atunto ati atunṣe kọkọ waye, aijẹ bẹẹ, niṣe la n pọti ile ẹkan, ko si le seso rere.”

Bẹẹ ni baba ẹni ọdun mẹtalelaaadọrun-un naa sọ.

Leave a Reply