Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori bi awọn janduku ṣe fipa ba ọmọdebinrin kan, Mary Daramọla, laṣepọ, ti wọn si tun pa a niluu Alabata, nitosi Mọniya, nijọba ibilẹ Akinyẹle, n’Ibadan, Baale ilu naa, Oloye Julius Itanọla, ti rawọ ẹbẹ sawọn agbofinro lati ṣewadii iṣẹlẹ yii daadaa, ki wọn si fiya jẹ gbogbo awọn to lọwọ ninu ọran naa.
Nibi tọmọbinrin ọmọọdun mejidinlogun (18) naa ti n bọ lati ibi to ti lọọ ra irẹsi la gbọ pe awọn ọbayejẹ eeyan naa ti da a lọna ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun yii, ti wọn si fipa gbe e lọ sinu ile kan ti ko jinna sibẹ, wọn fipa ba a lo pọ, ki wọn too ran an lọ sọrun aremabọ.
Ohun to mu ki iṣẹlẹ yii ba awọn eeyan lojiiji ni pe ọwọ awọn agbofinro ti pada tẹ Sunday Shodipẹ, afurasi ọdaran to n pa kukuru pa gigun kaakiri agbgbe Akinyẹle, wọn si ti ro pe iku oro kan ko tun le pa ẹnikẹni mọ nijọba ibilẹ naa laimọ pe awọn ẹruuku mi-in tun fara pamọ sibi kan niluu Alabata, nijọba ibilẹ naa, ti wọn ko ti i jẹwọ ara wọn faye ri.
Wọn ni nibi tawọn ọdaju eeyan ọhun ti n gbiyanju lati lọọ gbe oku ọmọbinrin naa ju sibi kan lawọn eeyan ti ka wọn mọ, ti wọn si pariwo le wọn lori. Ariwo yii lawọn eeyan mi-in laduugbo naa gbọ ti wọn fi tu jade, ti wọn si mu eyi to n jẹ Toheeb Safẹjọ ninu awọn olubi eeyan naa, nigba ti awọn yooku sa lọ patapata.
Gẹgẹ bi iwadii akọroyin wa ṣe fidi ẹ mulẹ, ailera ọpọlọ n ṣe Iya Mary. Iya ọkọ ẹ, Abilekọ Adedeji Folukẹ, ẹni tawọn eeyan mọ si Iya Adua ni ṣọọṣi Kerubu ati Ṣerafu to wa niluu Alabata lo n tọju ẹ.
Inu yara kan ninu ile ti wọn n kọ lọwọ lẹgbẹẹ ṣọọṣi Kerubu ati Ṣerafu to wa niluu Alabata ni Mary atiya ẹ n gbe. Ọmọọdun mejidinlogun (18) ni Mary, o n kọṣẹ telọ lọwọ. Ipari ọdun yii ni iba ṣe firidọọmu. Awọn mẹta niya ẹ bi, oun si lakọbi, awọn aburo ẹ wa lọdọ baba wọn.
Iya baba Mary, Abilekọ Adedeji Folukẹ (Iya Adua), ṣalaye fun akọroyin wa pe “Lọjọ Mọnde yẹn, ni nnkan bii aago mẹjọ lalẹ, ni Mary sọ fun mi pe oun fẹẹ lọọ ra ráìsì ni titi nibẹ yẹn. Ẹyin igba yẹn ni wọn sare waa pe mi nile pe ki n waa wo o.
“Nigba ta a debẹ, oku ẹ la ba lori bẹẹdi ninu ile yẹn. Nigba ta a maa fi pada debẹ, nitori a kọkọ sare wa sile na, wọn ti gbe oku yẹn sọ kalẹ lori bẹẹdi ta a ti kọkọ ba a, wọn fẹẹ lọọ ju u nu la debẹ. Iro ẹsẹ wa ti wọn gbọ ni wọn fi sa lọ ko too di pe wọn ri ọkan ninu wọn to n jẹ Toheeb mu.”
Akọroyin wa gbiyanju lati ba Abilekọ Daramọla ti i ṣe Iya Mary gan-an sọrọ, ṣugbọn ailera obinrin naa ko jẹ ki akitiyan naa bọ si i nitori ipenija ilera to ni ko jẹ ko ri ọrọ gidi sọ.
Ọmọọdun mẹtadinlọgbọn (27) ni wọn pe Toheeb. Awakọ típà ni. Inu ilu yii lo n gbe, ṣugbọn ki i ṣọmọ ilu yii.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni afurasi ọdaran naa ti wa latimọle awọn agbofinro, nibi to ti n ran wọn lọwọ ninu iwadii ti wọn n ṣe lori iṣẹlẹ yii.
Nigba to n bakọroyin wa sọrọ, Bale Alabata, Oloye Julius Ọladokun Itanọla, sọ pe afurasi ọdaran naa ki i ṣọmọ ilu oun, bo tilẹ jẹ pe Alabata nibẹ naa lo n gbe, to si ti n ṣiṣẹ.
O waa rọ awọn agbofinro lati ṣewadii iṣẹlẹ ọhun daadaa, ki wọn si mu awọn afurasi ọdaran yooku ti wọn gbimọ-pọ pẹlu Toheeb lati huwa ọdaran naa ki wọn too na papa bora.
Eyin Olopa e jowo se ise yin biise o