Afi ki Buhari jade ko waa ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ o-Atiku

Jide Kazeem

Igbakeji Aarẹ orilẹ-ede yii tẹlẹ, Atiku Abubakar, ti sọ pe ohun ibanujẹ nla lo jẹ bi awọn ṣoja ṣe pa awọn ọdọ nipakupa lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Ninu ọrọ ẹ lo ti sọ pe ninu ibanujẹ ati iporuuru ọkan loun wa nigba ti oun ri ohun to ṣẹlẹ sawọn ọdọ Naijiria to n ṣewọde naa.

O loun ko ṣai ba awọn mọlẹbi ti wọn padanu awọn ọmọ to ṣubu loju ija kẹdun gidigidi, ati pe ọpọ irufẹ ile bẹẹ ni wọn ti n sunkun, ti ibanujẹ si dori ọpọ kodo bayii.

Atiku lohun to yẹ Aarẹ orilẹ-ede yii, Muhammed Buhari bayii ni ko bọ sita, ko ba awọn eeyan sọrọ, ki awọn ẹṣọ agbofinro paapaa sinmi, ki wọn yee doju ija kọ awọn araalu to yẹ ki wọn daabo bo.

Ọkunrin naa lo yẹ ki ijọba ṣiṣẹ lori awọn ohun ti awọn ọdọ yii n beere fun, dipo ipakupa tawọn ṣoja ti ijọba Buhari ko sita n pa awọn ọdọ kiri.

 

Leave a Reply