Afi ki Buhari tete gbe igbesẹ lati da orileede yii pada ni bebe iṣubu to wa ko too pẹ ju-Ortom

Faith Adebọla

Ọjọ pataki ni ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kejila, jẹ nigbesi aye olori orileede wa, Ajagun-fẹyinti Buhari, ọjọ naa lọjọọbi ẹ, oriṣiiriṣii iṣẹ ikini kuu oriire ati igboṣuba fun ni lo si ti n rọjo bi Buhari ṣe di ẹni ọdun mọkandinlọgọrin loke eepẹ.

Ṣugbọn amọran ni Gomina ipinlẹ, Samuel Ortom, fi ikini tiẹ ṣe, o ni awọn to rọgba yi Aarẹ ki i ṣe oloootọ eeyan, irọ ni wọn n pa fun Buhari nipa bi nnkan ṣe ri ni Naijiria, paapaa lori ipenija eto aabo to dẹnu kọlẹ lasiko yii, o si rọ Buhari lati gbọn eti nu lọdọ awọn afi-dudu-pe-funfun ti wọn n gba a lamọran, ko wa nnkan gidi ṣe siṣoro naa.

Bayii ni Ortom ṣe sọrọ ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin rẹ, Nathaniel Ikyur, fi lede lọjọ Satide, lorukọ ọga rẹ, o ni:

“Mo darapọ mọ awọn mọlẹbi, ọrẹ, awọn oloṣelu ati gbogbo ọmọ Naijiria lati ki ẹ kuu oriire ọjọọbi ọdun mọkandinlọgọrin yin o.

“Baba ni Aarẹ jẹ sawọn eeyan kan, baba agba ni sawọn mi-in, awọn kan si ka a si baba baba baba, to yẹ ko mọ pe Naijiria ti fẹyin balẹ bayii pẹlu ọṣẹ nla ti awọn agbebọn, awọn afẹmiṣofo, ati awọn ajinigbe n ṣe, wọn ti fẹẹ yẹ iṣọkan ati alaafia orileede yii kuro lori ipilẹ rẹ.

“Ojoojumọ ni wọn n dumbu eeyan bii ẹni dumbu ewurẹ, bo ṣe lọna oko, lọna irin-ajo, ninu ile wọn, pipa bii ẹran ni, aya si tun ko wọn debii pe wọn ṣe fidio ti oju awọn apaayan naa han rekete, sibẹ wọn o ti i ri wọn mu.

“Awọn oju popo ti di pakute iku, ko sẹni to fẹẹ gba titi mọ, pẹlu ibẹrubojo ni, tori awọn ajinigbe ti wọn maa fi wọn pawo, tabi ki wọn ṣeku pa wọn. Ko tiẹ waa sibi kan to laabo mọ lorileede yii.

“Aarẹ o gbọdọ tun maa tẹti sawọn afi-dudu-pe-funfun to rọgba yi i ka mọ, to jẹ orin ko sewu loko ni wọn n kọ si i leti o. Ewu nbẹ nile loko ni lasiko yii, Naijiria ko fara rọ rara.

“Afi ki Mista Purẹsidenti tete gbe igbesẹ lati da orileede yii pada ni bebe iṣubu to wa ko too pẹ ju. Iṣẹ ikini temi ni fun un niyẹn o.”

Bẹẹ ni Ortom wi.

Leave a Reply