Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti sọ pe bi orileede Naijiria ṣe tete gba ominira lọwọ awọn oyinbo amunisin lo fa a to fi bọ sọwọ awọn ọdaju ati alainibẹru adari.
Ọba Akanbi sọrọ yii ninu ọrọ to fi sita layaajọ ọdun kejilelọgọta ti orileede Naijiria gba ominira. O ni gbogbo wahala to n koju orileede yii bayii ko ṣẹyin bi awọn oloṣelu atawọn adari ṣe n dari wa nitori o yẹ ki Naijiria ti goke agba ju bayii lọ.
Ọba yii ṣalaye pe nnkan ko buru bayii nigba ti a wa lasiko ijọba Biritiko, o si yẹ ko to bii ọdun 2000 siwaju ki orileede yii to gba ominira.
Oluwoo banujẹ lori ipo ikaaanu ti orileede yii wa bayii, o si sọ pe ki Ọlọrun san ẹsan iwa awọn adari wa fun wọn gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe fun orileede yii.
O fi kun ọrọ rẹ ninu atẹjade ti Akọwe iroyin rẹ, Alli Ibraheem, fi sita pe, “Ko si nnkan idunnu kankan ninu ayajọ ọdun kejilelọgọta ti Naijiria ti gba ominira, ohun to si buru ni pe a ti tete gba ominira ju, a waa fi ọjọ-ọla wa le awọn alailaanu adari lọwọ.
“Pupọ awọn adari wa ni wọn jẹ onimọtaraẹni nikan, alaikunju oṣuwọn ati ẹni ti ko bẹru Ọlọrun rara. Afi ki Ọlọrun ṣedajọ wọn pẹlu ọwọ ti wọn fi mu ọrọ Naijiria.
“Mo pe wọn nija lati bọ sita, ki wọn ṣalakalẹ gbogbo nnkan ti wọn ti ṣe fun orileede yii. Ni gbogbo ayajọ ọjọ ominira, o yẹ ka maa fi asiko silẹ fun wọn lati sọ iru igbega ti wọn ti mu ba orileede yii. O yẹ ka ti goke ju bayii lọ. A ni oniruuru nnkan lati jẹ ọkan lara awọn orileede to goke agba ju lọ, ṣugbọn aṣiyan awọn adari la ni.
“Gẹgẹ bii ori-ade, mo le fi awọn aṣeyọri mi lori itẹ yanga. Mi i gba ohunkohun lọwọ awọn eeyan mi. Gbogbo igba ni mo maa n ja fun ẹtọ wọn. Mo maa n jiyin iṣẹ iriju mi, mo si maa n sọ fun wọn ni gbogbo igba lati maa ko mi loju ti mo ba gba oogun-oju wọn. Mo le fọwọ sọya gẹgẹ bii ọkan lara awọn adari rere lonii.
“Imọran mi fun awọn oloṣelu atawọn adari ti wọn wa ni ipo agbara bayii ni pe ki wọn ronu piwada, ki wọn si tun orileede yii ṣe. Mo nigbagbọ pe a le tun ẹru wa ko latisalẹ.
“Ki awọn ọmọ Naijiria bẹrẹ si i dibo yan awọn eeyan ti wọn kunju osunwọn sipo aṣẹ, ki wọn si maa beere iṣẹ iriju wọn. A lagbara lati yọ adari tiṣejọba rẹ ba di egun (curse) fun wa.
“Ẹ jẹ ka le awọn adari ti wọn ko ni ẹri ọkan danu. Loootọ lo ti pẹ ju, ṣugbọn ko ti i bọ fun wa.”