Agbanah dẹ agbaana sawọn oyinbo Amẹrika, nile-ẹjọ ba sọ ọ sẹwọn oṣu mẹfa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọpọ oyinbo ara Amẹrika lo ti n ṣiṣẹ erin, ṣugbọn ti wọn n jẹ̀jẹ ẹ̀líírí. Ki i ṣe páyé lo n ṣe wọn, ọmọ Naijiria wa nihin-in, Tọba Agbanah, lo dẹ agbaana sinu owo wọn pẹlu bo ṣe maa n fọgbọn alumọkọroyi gba pupọ ninu owo iṣẹ ti wọn n ṣe.

Lẹyin ọdun bii meloo kan to ti n huwa àwòdì-jẹun-èpè sanra rẹ ọhun, ibẹrẹ odun to kọja laṣiiri ẹ too tu sawọn oyinbo lọwọ, ti wọn si fẹjọ ẹ sun EFCC, iyẹn ajọ to n gbogun ti jibiti owo ati iwa magomago nilẹ yii, ọdun 2019 ọhun si ti n pari lọ ki ọwọ awọn agbofinro too tẹ ẹ. EFCC ko si ṣe meni ṣe meji, ile-ẹjọ ni wọn gbe e lọ taara.

Yatọ si awọn nnkan ribiribi to ti fowo dá lárà, owo ti wọn ba ninu aṣunwọn ifowopamọ ọkunrin yii jẹ miliọnu mejila ati ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira (N12.1).

Lẹyin atotonu agbẹjọro jaguda yii pẹlu awọn amofin ajọ EFCC,  Onidaajọ Patricia Ajoku ti ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan, dajọ lọjọ Ẹti to kọja, o ni ki ọmọkunrin naa lọọ fẹwọn oṣu mẹfa jura.

Ṣaaju l’Amofin Benedict Ubi ti i ṣe agbẹjọro ajọ EFCC ti ṣalaye fun ile-ẹjọ pe o pẹ ti Tọba ti maa n fara pamọ lu awọn oyinbo ara Amẹrika ni jibiti lori ẹrọ ayelujara, ọpọ ẹsun ni wọn si ti fi kan an lọdọ EFCC ko too di pe ọwọ tẹ ẹ lọjọ kẹta, oṣu kẹwaa, ọdun 2019.

Agbẹjọro to ti gboye ọmọwe ninu imọ ofin yii ṣalaye fun ile-ẹjọ pe owo nla nla lawọn oyinbo Amẹrika fi maa n ranṣẹ sinu aṣunwọn GTB ati Eco Bank ọdaran yii lẹyin to ba ti fi atẹranṣẹ to kun fun irọ ati eitanjẹ ṣọwọ si wọn nipasẹ adirẹsi imeeli rẹ, ko si tori ohun meji ṣagbekalẹ imeeli yii ju jibiti lilu naa lọ.

“Diẹ ninu awọn dukia to ti fi owo gbaju-ẹ to n ṣe yii kojọ ni ọkọ olowo nla kan ti wọn n pe ni Venza, ọkọ ayọkẹlẹ Toyota, awọn laptọọpu, ọpọlọpọ foonu olowo nla ati tẹlifiṣan.”

Amofin naa sọ pe ọran ti ọdaran yii da la ijiya lọ labẹ ori kejilelogun (22), ipin B ninu ofin orileede yii ọdun 2015, eyi to to ṣe jibiti lilu leewọ.

Ninu igbẹjọ to ti waye ṣaaju lolujẹjọ ti jẹwọ pe oun jẹbi, to si ti gba lati da diẹ ninu owo to fi ọna alumọkọrọyi gba lọwọ awọn eeyan pada.

Eyi lo mu ki ajọ EFCC din ẹsun ti wọn fi kan an ni kootu ku si ọkan ṣoṣo, dipo oriṣii ọgbọn (30) ẹsun ti wọn fi kan an nibẹrẹ ẹjọ naa.

Toun ti bẹẹ naa, Onidaajọ Ajoku tun fi ẹwọn oṣu mẹfa da sẹria fun ọkunrin onijibiti naa.

Leave a Reply